Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| AHABU si sọ ohun gbogbo, ti Elijah ti ṣe, fun Jesebeli, ati pẹlu bi o ti fi idà pa gbogbo awọn woli. |
| 2 |
| Nigbana ni Jesebeli rán onṣẹ kan si Elijah, wipe, Bẹ̃ni ki awọn òriṣa ki o ṣe si mi ati jù bẹ̃ lọ pẹlu, bi emi kò ba ṣe ẹmi rẹ dabi ọkan ninu wọn ni iwoyi ọla. |
| 3 |
| O si bẹ̀ru, o si dide, o si lọ fun ẹmi rẹ̀, o si de Beerṣeba ti Juda, o si fi ọmọ-ọdọ rẹ̀ silẹ nibẹ. |
| 4 |
| Ṣugbọn on tikararẹ̀ lọ ni irin ọjọ kan si aginju, o si wá, o si joko labẹ igi juniperi kan, o si tọrọ fun ara rẹ̀ ki on ba le kú; o si wipe, O to; nisisiyi, Oluwa, gba ẹmi mi kuro nitori emi kò sàn jù awọn baba mi lọ! |
| 5 |
| Bi o si ti dùbulẹ ti o si sùn labẹ igi juniperi kan, si wò o, angeli fi ọwọ́ tọ́ ọ, o si wi fun u pe, Dide, jẹun. |
| 6 |
| O si wò, si kiyesi i, àkara ti a din lori ẹyin iná, ati orù-omi lẹba ori rẹ̀: o si jẹ, o si mu, o si tun dùbulẹ. |
| 7 |
| Angeli Oluwa si tun pada wá lẹrinkeji, o si fi ọwọ́ tọ́ ọ, o si wipe, Dide, jẹun; nitoriti ọ̀na na jìn fun ọ. |
| 8 |
| O si dide, o si jẹ, o mu, o si lọ li agbara onjẹ yi li ogoji ọsan ati ogoji oru si Horebu, oke Ọlọrun. |
| 9 |
| O si de ibẹ̀, si ibi ihò okuta, o si wọ̀ sibẹ, si kiyesi i, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Kini iwọ nṣe nihinyi, Elijah? |
| 10 |
| On si wipe, Ni jijowu emi ti njowu fun Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun: nitoriti awọn ọmọ Israeli ti kọ̀ majẹmu rẹ silẹ, nwọn ti wó awọn pẹpẹ rẹ lulẹ, nwọn si ti fi idà pa awọn woli rẹ: ati emi, ani emi nikanṣoṣo li o kù, nwọn si nwá ẹmi mi lati gba a kuro. |
| 11 |
| O si wipe, Jade lọ, ki o si duro lori oke niwaju Oluwa. Si kiyesi i, Oluwa kọja, ìji nla ati lile si fà awọn oke nla ya, o si fọ́ awọn apata tũtu niwaju Oluwa; ṣugbọn Oluwa kò si ninu iji na: ati lẹhin iji na, isẹlẹ; ṣugbọn Oluwa kò si ninu isẹlẹ na. |
| 12 |
| Ati lẹhin isẹlẹ na, iná; ṣugbọn Oluwa kò si ninu iná na, ati lẹhin iná na, ohùn kẹ́lẹ kekere. |
| 13 |
| O si ṣe, nigbati Elijah gbọ́, o si fi agbáda rẹ̀ bo oju rẹ̀, o si jade lọ, o duro li ẹnu iho okuta na. Si kiyesi i, ohùn kan tọ̀ ọ wá wipe, Kini iwọ nṣe nihinyi Elijah? |
| 14 |
| On si wipe, Ni jijowu, emi ti njowu fun Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun: nitoriti awọn ọmọ Israeli ti kọ̀ majẹmu rẹ silẹ, nwọn si ti wó awọn pẹpẹ rẹ lulẹ, nwọn si ti fi idà pa awọn woli rẹ; ati emi, ani emi nikanṣoṣo li o kù; nwọn si nwá ẹmi mi lati gba a kuro. |
| 15 |
| Oluwa si wi fun u pe, Lọ, pada li ọ̀na rẹ, kọja li aginju si Damasku: nigbati iwọ ba de ibẹ, ki o si fi ororo yan Hasaeli li ọba lori Siria. |
| 16 |
| Ati Jehu, ọmọ Nimṣi ni iwọ o fi ororo yàn li ọba lori Israeli: ati Eliṣa, ọmọ Ṣafati, ara Abel-Mehola ni iwọ o fi ororo yan ni woli ni ipò rẹ. |
| 17 |
| Yio si ṣe, ẹniti o ba sala kuro lọwọ idà Hasaeli ni Jehu yio pa, ati ẹniti o ba sala kuro lọwọ idà Jehu ni Eliṣa yio pa. |
| 18 |
| Ṣugbọn emi ti kù ẹ̃dẹgbarin enia silẹ fun ara mi ni Israeli, gbogbo ẽkun ti kò tii kunlẹ fun Baali, ati gbogbo ẹnu ti kò iti fi ẹnu kò o li ẹnu. |
| 19 |
| Bẹ̃ni o pada kuro nibẹ, o si ri Eliṣa, ọmọ Ṣafati o nfi àjaga malu mejila tulẹ niwaju rẹ̀, ati on na pẹlu ikejila: Elijah si kọja tọ̀ ọ lọ, o si da agbáda rẹ̀ bò o. |
| 20 |
| O si fi awọn malu silẹ o si sare tọ̀ Elijah lẹhin o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi lọ ifi ẹnu kò baba ati iya mi li ẹnu, nigbana ni emi o tọ̀ ọ lẹhin. O si wi fun u pe, Lọ, pada, nitori kini mo fi ṣe ọ? |
| 21 |
| O si pada lẹhin rẹ̀, o si mu àjaga malu kan, o si pa wọn, o si fi ohun-elo awọn malu na bọ̀ ẹran wọn, o si fi fun awọn enia, nwọn si jẹ. On si dide, o si tẹle Elijah lẹhin, o si ṣe iranṣẹ fun u. |
|
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/1kings/019.mp3
22
19