O si wi fun Jehoṣafati pe, Iwọ o ha bá mi lọ si ogun Ramoti-Gileadi bi? Jehoṣafati si wi fun ọba Israeli pe, Emi bi iwọ, enia mi bi enia rẹ, ẹṣin mi bi ẹṣin rẹ.
Nigbana ni ọba Israeli kó awọn woli jọ, bi irinwo ọkunrin, o si wi fun wọn pe, Ki emi ki o ha lọ si Ramoti-Gileadi lọ ijagun, tabi ki emi ki o jọwọ rẹ̀? Nwọn si wipe, Goke lọ: nitoriti Oluwa yio fi i le ọba lọwọ.
Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, ọkunrin kan Mikaiah, ọmọ Imla, mbẹ sibẹ, lọdọ ẹniti awa iba bère lọwọ Oluwa: ṣugbọn emi korira rẹ̀, nitori kì isọ asọtẹlẹ ire si mi, bikoṣe ibi. Jehoṣafati si wipe, Ki ọba má sọ bẹ̃.
Ọba Israeli ati Jehoṣafati, ọba Juda joko olukulùku lori itẹ́ rẹ̀, nwọn wọ̀ aṣọ igunwa wọn ni ita ẹnu-bode Samaria, gbogbo awọn woli na si nsọtẹlẹ niwaju wọn.
Onṣẹ ti o lọ ipè Mikaiah wi fun u pe, Kiyesi i nisisiyi, ẹnu kanna ni ọ̀rọ awọn woli fi jẹ rere fun ọba: emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ọ̀rọ rẹ ki o dabi ọ̀rọ ọkan ninu wọn, ki o si sọ rere.
Bẹ̃ni o de ọdọ ọba. Ọba si wi fun u pe, Mikaiah, ki awa o ha lọ si Ramoti-Gileadi lọ ijagun, tabi ki a jọwọ rẹ̀? O si da a lohùn pe, Lọ, ki o si ṣe rere: nitori Oluwa yio fi i le ọba lọwọ.
On si wipe, Mo ri gbogbo Israeli tukakiri lori awọn oke bi agutan ti kò ni oluṣọ: Oluwa si wipe, Awọn wọnyi kò ni oluwa, jẹ ki nwọn ki o pada olukuluku si ile rẹ̀ li alafia.
Oluwa si wi fun u pe, Bawo? O si wipe, Emi o jade lọ, emi o si di ẹmi-eke li ẹnu gbogbo awọn woli rẹ̀. On si wipe, Iwọ o tàn a, iwọ o si bori pẹlu: jade lọ, ki o si ṣe bẹ̃.
Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, Emi o pa aṣọ dà, emi o si lọ si oju ija; ṣugbọn iwọ gbé aṣọ igunwà rẹ wọ̀. Ọba Israeli si pa aṣọ dà, o si lọ si oju ijà.
Ṣugbọn ọba Siria paṣẹ fun awọn olori-kẹkẹ́ rẹ̀, mejilelọgbọn, ti o ni aṣẹ lori kẹkẹ́ rẹ̀ wipe, Máṣe ba ẹni-kekere tabi ẹni-nla jà, bikoṣe ọba Israeli nikan.
Ọkunrin kan si fà ọrun rẹ̀ laipete, o si ta ọba Israeli lãrin ipade ẹwu-irin; nitorina li o ṣe wi fun olutọju-kẹkẹ́ rẹ̀ pe, Yi ọwọ́ rẹ dà, ki o si mu mi jade kuro ninu ogun; nitoriti emi gbọgbẹ.
O si rin ni gbogbo ọ̀na Asa baba rẹ̀; kò yipada kuro ninu rẹ̀, o nṣe eyiti o tọ li oju Oluwa: kiki a kò mu awọn ibi giga kuro; awọn enia si nrú ẹbọ, nwọn si nsun turari sibẹ̀ ni ibi giga wọnni.