Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| AHABU si ni ãdọrin ọmọ ọkunrin ni Samaria. Jehu si kọwe, o si ranṣẹ si Samaria si awọn olori Jesreeli, si awọn àgbagba, ati si awọn ti ntọ́ awọn ọmọ Ahabu, wipe, |
| 2 |
| Njẹ nisisiyi nigbati iwe yi ba ti de ọdọ nyin, bi o ti jẹpe, awọn ọmọ oluwa nyin mbẹ lọdọ nyin, ati kẹkẹ́ ati ẹṣin mbẹ lọdọ nyin, ilu olodi pẹlu ati ihamọra. |
| 3 |
| Ki ẹ wò ẹniti o sàn jùlọ ati ti o si yẹ jùlọ ninu awọn ọmọ oluwa nyin, ki ẹ gbé e ka ori-itẹ́ baba rẹ̀, ki ẹ si jà fun ile oluwa nyin. |
| 4 |
| Ṣugbọn ẹ̀ru bà wọn gidigidi, nwọn si wipe, Kiyesi i, ọba meji kò duro niwaju rẹ̀: awa o ha ti ṣe le duro? |
| 5 |
| Ati ẹniti iṣe olori ile, ati ẹniti iṣe olori ilu, awọn àgbagba pẹlu, ati awọn olutọ́ awọn ọmọ, ranṣẹ si Jehu wipe, Iranṣẹ rẹ li awa, a o si ṣe gbogbo ohun ti o ba pa li aṣẹ fun wa; awa kì yio jẹ ọba: iwọ ṣe eyi ti o dara li oju rẹ. |
| 6 |
| Nigbana ni o kọ iwe lẹrinkeji si wọn wipe, Bi ẹnyin ba ṣe ti emi, bi ẹnyin o si fi eti si ohùn mi, ẹ mu ori awọn ọkunrin na, awọn ọmọ oluwa nyin, ki ẹ si tọ̀ mi wá ni Jesreeli ni iwòyi ọla. Njẹ awọn ọmọ ọba, ãdọrin ọkunrin, mbẹ pẹlu awọn enia nla ilu na ti ntọ́ wọn. |
| 7 |
| O si ṣe, nigbati iwe na de ọdọ wọn, ni nwọn mu awọn ọmọ ọba, nwọn si pa ãdọrin ọkunrin, nwọn si kó ori wọn sinu agbọ̀n, nwọn si fi wọn ranṣẹ si i ni Jesreeli. |
| 8 |
| Onṣẹ kan si de, o si sọ fun u, wipe, nwọn ti mu ori awọn ọmọ ọba wá. On si wipe, Ẹ tò wọn li okiti meji ni atiwọ̀ ẹnu bodè, titi di owurọ̀. |
| 9 |
| O si ṣe li owurọ̀, o si jade lọ, o si duro, o si wi fun gbogbo awọn enia pe, Olododo li ẹnyin: kiyesi i, emi ṣọ̀tẹ si oluwa mi, mo si pa a: ṣugbọn tani pa gbogbo awọn wọnyi? |
| 10 |
| Njẹ ẹ mọ̀ pe, kò si ohunkan ninu ọ̀rọ Oluwa, ti Oluwa sọ niti ile Ahabu ti yio bọ́ silẹ, nitori ti Oluwa ti ṣe eyi ti o ti sọ nipa ọwọ Elijah iranṣẹ rẹ̀. |
| 11 |
| Bẹ̃ni Jehu pa gbogbo awọn ti o kù ni ile Ahabu ni Jesreeli ati gbogbo awọn enia nla rẹ̀, ati awọn ibatan rẹ̀, ati awọn alufa rẹ̀, titi on kò fi kù ọkan silẹ fun u. |
| 12 |
| On si dide, o si mbọ̀ o si wá si Samaria: bi o si ti wà nibi ile irẹ́run agutan li oju ọ̀na. |
| 13 |
| Jehu pade awọn arakunrin Ahasiah ọba Juda, o si wipe, Tali ẹnyin? Nwọn si dahùn wipe, Awa arakunrin Ahasiah ni; awa si nsọ̀kalẹ lati lọ ikí awọn ọmọ ọba ati awọn ọmọ ayaba. |
| 14 |
| On si wipe, Ẹ mu wọn lãyè, nwọn si mu wọn lãyè, nwọn si pa wọn nibi iho ile irẹ́run agùtan, ani ọkunrin mejilelogoji, bẹ̃ni kò si kù ẹnikan wọn. |
| 15 |
| Nigbati o si jade nibẹ, o ri Jehonadabu ọmọ Rekabu mbọ̀wá ipade rẹ̀; o si sure fun u, o si wi fun u pe, Ọkàn rẹ ha ṣe dede bi ọkàn mi ti ri si ọkàn rẹ? Jehonadabu si dahùn wipe, Bẹ̃ni. Bi bẹ̃ni, njẹ fun mi li ọwọ rẹ. O si fun u li ọwọ rẹ̀; on si fà a sọdọ rẹ̀ sinu kẹkẹ́. |
| 16 |
| On si wipe, Ba mi lọ ki o si wò itara mi fun Oluwa. Bẹ̃ni nwọn mu u gùn kẹkẹ́ rẹ̀. |
| 17 |
| Nigbati o si de Samaria, o pa gbogbo awọn ti o kù fun Ahabu ni Samaria, titi o fi run u, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa ti o sọ fun Elijah. |
| 18 |
| Jehu si kó gbogbo awọn enia jọ, o si wi fun wọn pe, Ahabu sìn Baali diẹ, ṣugbọn Jehu yio sìn i pupọ. |
| 19 |
| Njẹ nitorina, ẹ pè gbogbo awọn woli Baali fun mi, gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, ati gbogbo awọn alufa rẹ̀; máṣe jẹ ki ọkan ki o kù; nitoriti mo ni ẹbọ nla iṣe si Baali: ẹnikẹni ti o ba kù, kì yio yè. Ṣugbọn Jehu fi ẹ̀tan ṣe e, nitori ki o le pa awọn olùsin Baali run. |
| 20 |
| Jehu si wipe, Ẹ yà apejọ si mimọ́ fun Baali; nwọn si kede rẹ̀. |
| 21 |
| Jehu si ranṣẹ si gbogbo Israeli; gbogbo awọn olùsin Baali si wá tobẹ̃ ti kò si kù ọkunrin kan ti kò wá. Nwọn si wá sinu ile Baali; ile Baali si kún lati ikangun ekini titi de ekeji. |
| 22 |
| On si wi fun ẹniti o wà lori yará babaloriṣa pe, Kó aṣọ wá fun gbogbo awọn olùsin Baali. On si kó aṣọ jade fun wọn wá. |
| 23 |
| Jehu si lọ, ati Jehonadabu ọmọ Rekabu sinu ile Baali, o si wi fun awọn olùsin Baali pe, Ẹ wá kiri, ki ẹ si wò ki ẹnikan ninu awọn iranṣẹ Oluwa ki o má si pẹlu nyin nihin, bikòṣe kìki awọn olùsin Baali. |
| 24 |
| Nigbati nwọn si wọle lati ru ẹbọ ati ọrẹ-sisun, Jehu yàn ọgọrin ọkunrin si ode, o si wipe, Bi ẹnikan ninu awọn ọkunrin ti mo mu wá fi le nyin lọwọ ba lọ, ẹniti o ba jẹ ki o lọ, ẹmi rẹ̀ yio lọ fun ẹmi tirẹ̀. |
| 25 |
| O si ṣe, bi a si ti pari ati ru ẹbọ sisun, ni Jehu wi fun awọn olùṣọ ati awọn olori-ogun pe, Wọle, ki ẹ si pa wọn; ẹ máṣe jẹ ki ẹnikan ki o jade. Nwọn si fi oju idà pa wọn; awọn olùṣọ ati awọn olori-ogun si gbé wọn sọ si ode, nwọn si wọ̀ inu odi ile Baali. |
| 26 |
| Nwọn si kó awọn ere lati ile Baali jade, nwọn si sun wọn. |
| 27 |
| Nwọn si wo ere Baali lulẹ, nwọn si wo ile Baali lulẹ, nwọn si ṣe e ni ile igbẹ́ titi di oni yi. |
| 28 |
| Bayi ni Jehu pa Baali run kuro ni Israeli. |
| 29 |
| Ṣugbọn Jehu kò kuro ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ti o mu Israeli ṣẹ̀, eyinì ni, awọn ẹgbọ̀rọ malu wura ti o wà ni Beteli, ati eyiti o wà ni Dani. |
| 30 |
| Oluwa si wi fun Jehu pe, Nitoriti iwọ ti ṣe rere ni ṣiṣe eyi ti o tọ́ li oju mi, ti o si ti ṣe si ile Ahabu gẹgẹ bi gbogbo eyiti o wà li ọkàn mi, awọn ọmọ rẹ iran kẹrin yio joko lori itẹ Israeli. |
| 31 |
| Ṣugbọn Jehu kò ṣe akiyesi lati ma fi gbogbo ọkàn rẹ̀ rin ninu ofin Oluwa Ọlọrun Israeli: nitoriti kò yà kuro ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu, ti o mu Israeli ṣẹ̀. |
| 32 |
| Li ọjọ wọnni Oluwa bẹ̀rẹ si iké Israeli kuru: Hasaeli si kọlù wọn ni gbogbo agbègbe Israeli; |
| 33 |
| Lati Jordani nihà ilà-õrùn, gbogbo ilẹ Gileadi, awọn enia Gadi, ati awọn enia Reubeni, ati awọn enia Manasse, lati Aroeri, ti o wà leti odò Arnoni, ani Gileadi ati Baṣani. |
| 34 |
| Ati iyokù iṣe Jehu, ati gbogbo ohun ti o ṣe, ati gbogbo agbara rẹ̀, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli? |
| 35 |
| Jehu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀: nwọn si sìn i ni Samaria. Jehoahasi ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀. |
| 36 |
| Ọjọ ti Jehu jọba lori Israeli ni Samaria sì jẹ ọdun mejidilọgbọ̀n. |
|
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/2kings/010.mp3
25
10