Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| NIGBATI Ataliah iyá Ahasiah si ri pe ọmọ on kú, o dide, o si pa gbogbo iru-ọmọ ọba run. |
| 2 |
| Ṣugbọn Jehoṣeba ọmọbinrin Joramu ọba, arabinrin Ahasiah, mu Joaṣi ọmọ Ahasiah, o si ji i gbé kuro ninu awọn ọmọ ọba ti a pa; nwọn si pa a mọ́ ninu iyẹ̀wu kuro lọdọ Ataliah, on, ati alagbatọ́ rẹ̀, ti a kò si fi pa a. |
| 3 |
| A si pa a mọ́ pẹlu rẹ̀ ni ile Oluwa li ọdun mẹfa. Ataliah si jọba lori ilẹ na. |
| 4 |
| Li ọdun keje Jehoiada si ranṣẹ o si mu awọn olori lori ọ̀rọrún, pẹlu awọn balogun, ati awọn olùṣọ, o si mu wọn wá si ọdọ rẹ̀ sinu ile Oluwa, o si ba wọn da majẹmu, o si mu wọn bura ni ile Oluwa, o si fi ọmọ ọba hàn wọn. |
| 5 |
| O si paṣẹ fun wọn wipe, Eyi ni nkan ti ẹnyin o ṣe; Idamẹta nyin ti nwọle li ọjọ isimi, yio ṣe olùtọju iṣọ ile ọba; |
| 6 |
| Idamẹta yio si wà li ẹnu ọ̀na Suri; idamẹta yio si wà li ẹnu-ọ̀na lẹhin ẹ̀ṣọ: bẹ̃li ẹnyin o tọju iṣọ́ ile na, lati da abo bò o. |
| 7 |
| Ati idajì gbogbo ẹnyin ti njade lọ li ọjọ isimi, ani awọn ni yio tọju iṣọ ile Oluwa yi ọba ka. |
| 8 |
| Ẹnyin o si pa agbo yi ọba ka, olukuluku pẹlu ohun ijà rẹ̀ li ọwọ rẹ̀: ẹniti o ba si wọ̀ arin ẹgbẹ́ ogun na, ki a pa a: ki ẹnyin ki o si wà pẹlu ọba bi o ti njade lọ, ati bi o ti mbọ̀wá ile. |
| 9 |
| Awọn olori ọrọrun ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti Jehoiada alufa pa li aṣẹ: olukuluku wọn si mu awọn ọkunrin tirẹ̀ ti ibá wọle wá li ọjọ isimi, pẹlu awọn ti iba jade lọ li ọjọ isimi, nwọn si wá si ọdọ Jehoiada alufa. |
| 10 |
| Alufa na si fi ọ̀kọ ati asà Dafidi ọba ti o wà ni ile Oluwa fun awọn olori ọ̀rọrún. |
| 11 |
| Awọn ẹ̀ṣọ si duro, olukulùku pẹlu ohun ijà rẹ̀ lọwọ rẹ̀ yi ọba ka, lati igun ọtún ile Oluwa, titi de igun osì ile Oluwa, nihà pẹpẹ ati ile Oluwa. |
| 12 |
| On si mu ọmọ ọba na jade wá o si fi ade de e lori, o si fun u ni iwe-ẹ̀ri; nwọn si fi i jọba, nwọn si fi ororo yàn a; nwọn si pàtẹwọ wọn, nwọn si wipe, Ki ọba ki o pẹ. |
| 13 |
| Nigbati Ataliah gbọ́ ariwo awọn ẹ̀ṣọ ati ti awọn enia, o tọ̀ awọn enia na wá ninu ile Oluwa. |
| 14 |
| Nigbati o si wò, kiyesi i, ọba duro ni ibuduro na, gẹgẹ bi iṣe wọn, ati awọn balogun, ati awọn afunpè duro lọdọ ọba; gbogbo enia ilẹ na si yọ̀, nwọn si fun ipè: Ataliah si fa aṣọ rẹ̀ ya, o si kigbe, pe, Ọtẹ̀! Ọtẹ̀! |
| 15 |
| Ṣugbọn Jehoiada alufa paṣẹ fun awọn olori ọ̀rọrún, ati awọn olori ogun, o si wi fun wọn pe, Ẹ mu u jade lati inu ile arin ẹgbẹ ogun: ẹniti o ba si tọ̀ ọ lẹhin ni ki ẹ fi idà pa. Nitoriti alufa na ti wipe, Ki a máṣe pa a ninu ile Oluwa. |
| 16 |
| Nwọn si gbé ọwọ le e; on si gbà ọ̀na ti awọn ẹṣin ngbà wọ̀ ile ọba: nibẹ ni a si pa a. |
| 17 |
| Jehoiada si da majẹmu lãrin Oluwa ati ọba ati awọn enia, pe, ki nwọn ki o mã ṣe enia Oluwa; ati lãrin ọba pẹlu awọn enia. |
| 18 |
| Gbogbo enia ilẹ na si lọ sinu ile Baali, nwọn si wo o lulẹ: awọn pẹpẹ rẹ̀ ati awọn ere rẹ̀ ni nwọn fọ́ tútu patapata, nwọn si pa Mattani alufa Baali niwaju pẹpẹ na. Alufa na si yàn awọn olori si ile Oluwa. |
| 19 |
| On si mu awọn olori ọ̀rọrún, ati awọn olori ogun, ati awọn ẹ̀ṣọ, ati gbogbo enia ilẹ na; nwọn si mu ọba sọ̀kalẹ lati ile Oluwa wá, nwọn si gbà oju ẹnu-ọ̀na ẹ̀ṣọ wọ̀ ile ọba. O si joko lori ìtẹ awọn ọba. |
| 20 |
| Gbogbo awọn enia ilẹ na si yọ̀, ilu na si tòro; nwọn si fi idà pa Ataliah li eti ile ọba. |
| 21 |
| Ẹni ọdun meje ni Jehoaṣi nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba. |
|
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/2kings/011.mp3
25
11