Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| NIGBANA ni gbogbo Israeli ko ara wọn jọ si ọdọ Dafidi ni Hebroni, wipe, Kiyesi i, egungun rẹ ati ẹran ara rẹ li awa iṣe. |
| 2 |
| Ati pẹlu li atijọ, ani nigbati Saulu jẹ ọba, iwọ li o nmu Israeli jade ti o si nmu u wá ile: Oluwa Ọlọrun rẹ si wi fun ọ pe, Ki iwọ ki o bọ Israeli, enia mi, ki iwọ ki o si ṣe ọmọ-alade lori Israeli enia mi. |
| 3 |
| Nitorina ni gbogbo awọn agbagba Israeli ṣe tọ ọba wá ni Hebroni; Dafidi si ba wọn da majẹmu ni Hebroni niwaju Oluwa; nwọn si fi ororo yan Dafidi li ọba lori Israeli, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa nipa ọwọ Samueli. |
| 4 |
| Ati Dafidi ati gbogbo Israeli jade lọ si Jerusalemu, ti iṣe Jebusi; awọn Jebusi ara ilẹ na ngbe ibẹ̀. |
| 5 |
| Awọn ara ilu Jebusi si wi fun Dafidi pe, Iwọ kò gbọdọ wọ̀ ihinyi wa. Ṣugbọn Dafidi kó ilu odi Sioni ti iṣe ilu Dafidi. |
| 6 |
| Dafidi si wipe, Ẹnikẹni ti o ba tetekọ kọlù awọn ara Jebusi ni yio ṣe olori ati balogun. Bẹ̃ni Joabu ọmọ Seruiah si tetekọ gòke lọ, o si jẹ olori. |
| 7 |
| Dafidi si ngbe inu ilu odi, nitorina ni nwọn fi npè e ni ilu Dafidi. |
| 8 |
| O si kọ́ ilu na yikakiri; ani lati Millo yikakiri: Joabu si tun iyokù ilu na ṣe. |
| 9 |
| Bẹ̃ni Dafidi nga, o si npọ̀ si i: nitori ti Oluwa awọn ọmọ-ogun wà pẹlu rẹ̀. |
| 10 |
| Wọnyi si ni olori awọn ọkunrin akọni ti Dafidi ni; awọn ti o fi ara wọn mọ ọ girigiri ni ijọba rẹ̀, pẹlu gbogbo Israeli, lati fi i jọba, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa fun Israeli. |
| 11 |
| Eyi ni iye awọn ọkunrin akọni ti Dafidi ni; Jaṣobeamu ọmọ Hakmoni, olori ninu awọn ọgbọ̀n balogun: on li o gbé ọ̀kọ rẹ̀ soke si ọ̃dunrun enia ti o pa lẹrikan. |
| 12 |
| Lẹhin rẹ̀ ni Eleaseri ọmọ Dodo, ara Ahohi, ẹniti iṣe ọkan ninu awọn akọni mẹta. |
| 13 |
| On wà pẹlu Dafidi ni Pasdammimu, nigbati awọn ara Filistia ko ara wọn jọ lati jagun, nibiti ilẹ-bĩri kan wà ti o kún fun ọkà barli; awọn enia si salọ kuro niwaju awọn ara Filistia. |
| 14 |
| Nwọn si duro jẹ li ãrin ilẹ-bĩri na, nwọn si gbà a, nwọn si pa awọn ara Filistia; Oluwa si fi igbala nla gbà wọn. |
| 15 |
| Awọn mẹta ninu awọn ọgbọ̀n balogun si sọ̀kalẹ tọ̀ Dafidi lọ sibi apata na, ninu iho Adullamu; ogun ara Filistia si do li afonifoji Refaimu. |
| 16 |
| Dafidi si mbẹ ninu ilu odi nigbana, ẹgbẹ-ogun awọn ara Filistia si mbẹ ni Betlehemu li akoko na. |
| 17 |
| Dafidi si pòngbẹ, o si wipe, Emi iba ri ẹni fun mi mu ninu omi kanga Betlehemu ti mbẹ leti ẹnu-bodè! |
| 18 |
| Awọn mẹta na si la inu ogun awọn ara Filistia kọja, nwọn si fa omi jade lati inu kanga Betlehemu, lati ẹnu-bodè, nwọn gbé e, nwọn si mu u tọ̀ Dafidi wá: Dafidi kò si fẹ mu u, ṣugbọn o tu u silẹ fun Oluwa, |
| 19 |
| O si wipe, Ki Ọlọrun mi má jẹ ki emi ki o ṣe eyi: ki emi ki o ha mu ẹ̀jẹ awọn ọkunrin wọnyi, ti nwọn fi ẹmi wọn wewu? nipa ẹmi wọn ni nwọn fi mu u wá. Nitorina ni on kò ṣe fẹ mu u, nkan wọnyi li awọn akọni mẹta wọnyi ṣe. |
| 20 |
| Ati Abiṣai arakunrin Joabu, on li olori ninu awọn mẹta: nitoriti o gbé ọ̀kọ rẹ̀ soke si ọ̃dunrun o pa wọn, o si ni orukọ ninu awọn mẹta. |
| 21 |
| O ni ọla jù awọn mẹta ẹgbẹ ekeji lọ o si jẹ olori wọn: ṣugbọn kò to awọn mẹta iṣaju. |
| 22 |
| Benaiah, ọmọ Jehoiada, ọmọ akọni ọkunrin kan ti Kabseeli, ẹniti o pọ̀ ni iṣe agbara, o pa awọn ọmọ Arieli meji ti Moabu; on sọkalẹ, o si pa kiniun kan ninu iho lakoko sno. |
| 23 |
| O si pa ara Egipti kan, ọkunrin ti o si sigbọnlẹ igbọnwọ marun ni gigun rẹ̀; ati li ọwọ ara Egipti na ni ọ̀kọ kan wà bi idubu igi awunṣọ; o si sọ̀kalẹ tọ ọ lọ pẹlu ọpa, a si já ọ̀kọ li ọwọ ara Egipti na, o si fi ọ̀kọ rẹ̀ pa a. |
| 24 |
| Nkan wọnyi ni Benaiah ọmọ Jehoiada ṣe, o si li orukọ ninu awọn akọni mẹta. |
| 25 |
| Kiyesi i, o li ọla jù awọn ọ̀gbọn lọ, ṣugbọn kò to awọn mẹta iṣaju. Dafidi si fi ṣe olori awọn igbimọ ile rẹ̀. |
| 26 |
| Awọn akọni ọkunrin ọmọ ogun rẹ̀ ni Asaheli arakunrin Joabu, Elhanani, ọmọ Dodo, ara Betlehemu. |
| 27 |
| Sammotu, ara Harori, Helesi, ara Peloni, |
| 28 |
| Ira, ọmọ Ikkeṣi, ara Tekoa, Abieseri ara Anatoti, |
| 29 |
| Sibbekai, ara Husa, Ilai, ara Ahohi, |
| 30 |
| Maharai, ara Netofa, Heledi ọmọ Baana, ara Netofa. |
| 31 |
| Itai ọmọ Ribai ti Gibea, ti awọn ọmọ Benjamini, Benaiah ara Piratoni, |
| 32 |
| Hurai ti odò Gaaṣi, Abieli ara Arbati, |
| 33 |
| Asmafeti ara Baharumi, Eliaba ara Ṣaalboni. |
| 34 |
| Awọn ọmọ Haṣemu ara Gisoni, Jonatani ọmọ Sage, ara Harari. |
| 35 |
| Ahihamu ọmọ Sakari, ara Harari, Elifali ọmọ Uri, |
| 36 |
| Heferi ara Mekerati, Ahijah ara Peloni, |
| 37 |
| Hesro ara Karmeli, Naari ọmọ Esbai, |
| 38 |
| Joeli arakunrin Natani, Mibhari ọmọ Haggeri, |
| 39 |
| Saleki ara Ammoni, Naharai ara Beroti, ẹniti nru ihamọra Joabu ọmọ Seruiah, |
| 40 |
| Ira ara Itri, Garobu ara Itri, |
| 41 |
| Uriah ara Heti, Sabadi ọmọ Ahalai, |
| 42 |
| Adina ọmọ Ṣisa ara Reubeni, olori awọn ara Reubeni, ati ọgbọ̀n enia pẹlu rẹ̀. |
| 43 |
| Hanani ọmọ Maaka, ati Jehoṣafati ara Mitini, |
| 44 |
| Ussia ara Aslerati, Ṣama ati Jegieli, awọn ọmọ Hotani, ara Aroeri, |
| 45 |
| Jediaeli ọmọ Simri, ati Joha arakunrin rẹ̀ ara Tisi, |
| 46 |
| Elieli ara Mahafi, ati Jeribai, ati Joṣafia, awọn ọmọ Elnaamu, ati Tima ara Moabu. |
| 47 |
| Elieli, ati Obedi, ati Jasieli ara Mesobah. |
|
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/1chronicles/011.mp3
29
11