Ati awọn ọmọ Tola; Ussi, ati Refaiah, ati Jerieli, ati Jamai, ati Jibsamu ati Samueli, awọn olori ile baba wọn, eyini ni ti Tola: akọni alagbara enia ni wọn ni iran wọn; iye awọn ẹniti o jẹ ẹgbã mọkanla o le ẹgbẹta li ọjọ Dafidi.
Ati pẹlu wọn, nipa iran wọn, gẹgẹ bi ile baba wọn, ni awọn ẹgbẹ ọmọ-ogun fun ogun, ẹgbã mejidilogun enia: nitoriti nwọn ni ọ̀pọlọpọ obinrin ati ọmọ ọkunrin.
Awọn ọmọ Bela; Esboni, ati Ussi, ati Ussieli ati Jerimoti ati Iri, marun; awọn olori ile baba wọn, akọni alagbara enia; a si kaye wọn nipa iran wọn si ẹgbãmọkanla enia o le mẹrinlelọgbọ̀n.
Awọn ọmọ Bekeri: Semira, ati Joaṣi, ati Elieseri, ati Elioeni, ati Omri, ati Jeremotu, ati Abiah, ati Anatoti, ati Alameti. Gbogbo wọnyi li awọn ọmọ Bekeri.
Ati Sabadi ọmọ rẹ̀, ati Ṣutela ọmọ rẹ̀, ati Eseri, ati Eleadi, ẹniti awọn ọkunrin Gati, ti a bi ni ilẹ na, pa, nitori nwọn sọkalẹ wá lati kó ẹran ọ̀sin wọn lọ.
Ati awọn ini ati ibugbe wọn ni Beteli, ati ilu rẹ̀, ati niha ìla-õrùn Naarani, niha ìwọ-õrùn Geseri pẹlu ilu rẹ̀: Ṣekemu pẹlu ati ilu rẹ̀, titi de Gasa ilu rẹ̀:
Ati leti ilu awọn ọmọ Manasse, Betṣeani, ati ilu rẹ̀, Taanaki ati ilu rẹ̀, Megiddo ati ilu rẹ̀, Dori ati ilu rẹ̀. Ninu awọn wọnyi li awọn ọmọ Josefu, ọmọ Israeli, ngbe.
Gbogbo awọn wọnyi li awọn ọmọ Aṣeri, awọn olori ile baba wọn, aṣayan alagbara akọni enia, olori ninu awọn ijoye. Iye awọn ti a kà yẹ fun ogun, ati fun ijà ni idile wọn jẹ, ẹgbã mẹtala ọkunrin.