Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| JEHOṢAFATI, ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀, o si mu ara rẹ̀ le si Israeli. |
| 2 |
| O si fi ogun sinu gbogbo ilu olodi Juda, o si fi ẹgbẹ-ogun si ilẹ Juda ati sinu ilu Efraimu wọnni, ti Asa baba rẹ̀ ti gbà. |
| 3 |
| Oluwa si wà pẹlu Jehoṣafati, nitoriti o rìn ninu ọ̀na iṣaju Dafidi, baba rẹ̀, kò si wá Baalimu: |
| 4 |
| Ṣugbọn o wá Ọlọrun baba rẹ̀, o si rìn ninu ofin rẹ̀, ki iṣe bi iṣe Israeli. |
| 5 |
| Nitorina ni Oluwa fi idi ijọba na mulẹ li ọwọ rẹ̀; gbogbo Juda si ta Jehoṣafati li ọrẹ, on si li ọrọ̀ ati ọlá li ọ̀pọlọpọ. |
| 6 |
| Ọkàn rẹ̀ si gbé soke li ọ̀na Oluwa: pẹlupẹlu o si mu ibi giga wọnni ati ere-oriṣa kuro ni Juda. |
| 7 |
| Ati li ọdun kẹta ijọba rẹ̀, o ranṣẹ si awọn ijoye rẹ̀, ani si Benhaili ati si Obadiah ati Sekariah, ati si Netaneeli, ati si Mikaiah, lati ma kọ́ni ninu ilu Juda wọnni. |
| 8 |
| Ati pẹlu wọn, o rán awọn ọmọ Lefi, ani Ṣemaiah, ati Netaniah, ati Sebadiah, ati Asaheli, ati Ṣemiramotu, ati Jehonatani, ati Adonijah, ati Tobijah, ati Tob-Adonijah, awọn ọmọ Lefi; ati pẹlu wọn Eliṣama, ati Jehoramu, awọn alufa. |
| 9 |
| Nwọn si kọ́ni ni Juda, nwọn si ni ofin Oluwa pẹlu wọn, nwọn si lọ kakiri ja gbogbo ilu Juda, nwọn si kọ́ awọn enia. |
| 10 |
| Ẹ̀ru Oluwa si ba gbogbo ijọba ilẹ na, ti o wà yikakiri Juda, tobẹ̃ ti nwọn kò ba Jehoṣafati jagun kan. |
| 11 |
| Ati ninu awọn ara Filistia mu ọrẹ fun Jehoṣafati wá, ati fadakà owo ọba: awọn ara Arabia si mu ọwọ́-ẹran fun u wá, ẹgbãrin àgbo o di ọ̃dunrun, ati ẹgbãrin obukọ di ọ̃dunrun. |
| 12 |
| Jehoṣafati si npọ̀ si i gidigidi: o si kọ́ ile olodi, ati ilu iṣura ni Juda. |
| 13 |
| O si ni iṣura pupọ ni ilu Juda; ati awọn jagunjagun, awọn alagbara akọni ọkunrin ti o wà ni Jerusalemu. |
| 14 |
| Wọnyi ni iye wọn gẹgẹ bi ile baba wọn: Ninu Juda, awọn olori ẹgbẹgbẹrun; Adna, olori, ati pẹlu rẹ̀, ọkẹ́ mẹ̃dogun alagbara akọni ọkunrin. |
| 15 |
| Ati atẹle rẹ̀ ni Jehohanani olori, ati pẹlu rẹ̀ ọkẹ mẹrinla ọkunrin. |
| 16 |
| Ati atẹle rẹ̀ ni Amasiah, ọmọ Sikri, ti o fi tinutinu fi ara rẹ̀ fun Oluwa; ati pẹlu rẹ̀ ọkẹ mẹwa alagbara akọni ọkunrin. |
| 17 |
| Ati ninu Benjamini; Eliada alagbara akọni ọkunrin, ati pẹlu rẹ̀ awọn enia ti nfi ọrun ati apata hamọra, ọkẹ mẹwa. |
| 18 |
| Ati atẹle rẹ̀ ni Jehosabadi, ati pẹlu rẹ̀ ọkẹ mẹsan, ti o mura silẹ de ogun. |
| 19 |
| Wọnyi nduro tì ọba, li aika awọn ti ọba fi sinu ilu olodi ni gbogbo Juda. |
|
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/2chronicles/017.mp3
36
17