Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| ẸNI ọdun mẹdọgbọn ni Hesekiah, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba fun ọdun mọkandilọgbọn ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Abijah, ọmọbinrin Sekariah. |
| 2 |
| O si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti Dafidi, baba rẹ̀, ti ṣe. |
| 3 |
| Li ọdun kini ijọba rẹ̀ li oṣù kini, o ṣí ilẹkun ile Oluwa, o si tun wọn ṣe. |
| 4 |
| O si mu awọn alufa wá ati awọn ọmọ Lefi, o si kó wọn jọ si ita ila-õrun. |
| 5 |
| O si wi fun wọn pe, Ẹ gbọ́ temi, ẹnyin ọmọ Lefi; ẹ yà ara nyin si mimọ́ nisisiyi, ki ẹ si yà ile Oluwa Ọlọrun awọn baba nyin si mimọ́, ki ẹ si kó ohun aimọ́ na jade kuro ni ibi mimọ́. |
| 6 |
| Awọn baba wa sa ti dẹṣẹ, nwọn si ti ṣe ibi li oju Oluwa Ọlọrun wa, nwọn si ti kọ̀ ọ silẹ, nwọn si ti yi oju wọn pada kuro ni ibugbe Oluwa, nwọn si ti pa ẹhin wọn da. |
| 7 |
| Nwọn ti tì ilẹkun iloro na pẹlu, nwọn si ti pa fitila, nwọn kò si sun turari, bẹ̃ni nwọn kò ru ẹbọ sisun ni ibi mimọ́ si Ọlọrun Israeli. |
| 8 |
| Nitorina ibinu Oluwa wà lori Juda ati Jerusalemu, o si fi wọn fun wàhala, ati iyanu ati ẹ̀sin, bi ẹnyin ti fi oju nyin ri. |
| 9 |
| Sa wò o, awọn baba wa ti ti ipa idà ṣubu, ati awọn ọmọkunrin wa, ati awọn ọmọbinrin wa, ati awọn obinrin wa wà ni igbekun nitori eyi. |
| 10 |
| Njẹ o wà li ọkàn mi lati ba Oluwa Ọlọrun Israeli dá majẹmu, ki ibinu rẹ̀ kikan ki o le yipada kuro lọdọ wa. |
| 11 |
| Ẹnyin ọmọ mi, ẹ máṣe jafara nisisiyi: nitori ti Oluwa ti yàn nyin lati duro niwaju rẹ̀, lati sìn i, ati ki ẹnyin ki o mã ṣe iranṣẹ fun u, ki ẹ si mã sun turari. |
| 12 |
| Nigbana li awọn ọmọ Lefi dide, Mahati, ọmọ Amasai, ati Joeli, ọmọ Asariah, ninu awọn ọmọ Kohati: ati ninu awọn ọmọ Merari, Kiṣi, ọmọ Abdi, ati Asariah, ọmọ Jehaleeli: ati ninu awọn ọmọ Gerṣoni, Joah, ọmọ Simma, ati Edeni, ọmọ Joah: |
| 13 |
| Ati ninu awọn ọmọ Elisafani, Ṣimri ati Jegieli: ati ninu awọn ọmọ Asafu, Sekariah ati Mattaniah. |
| 14 |
| Ati ninu awọn ọmọ Hemani, Jehieli ati Ṣimei: ati ninu awọn ọmọ Jedutuni, Ṣemaiah ati Ussieli. |
| 15 |
| Nwọn si kó awọn arakunrin wọn jọ, nwọn si yà ara wọn si mimọ́, nwọn si wá nipa aṣẹ ọba gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, lati gbá ile Oluwa mọ́. |
| 16 |
| Awọn alufa si wọ inu ile Oluwa lọhun lọ, lati gbá a mọ́, nwọn si mu gbogbo ẽri ti nwọn ri ninu tempili Oluwa jade si inu agbala ile Oluwa. Awọn ọmọ Lefi si kó o, nwọn si rù u jade gbangba lọ si odò Kidroni. |
| 17 |
| Njẹ nwọn bẹ̀rẹ li ọjọ kini oṣù kini, lati yà a si mimọ́, ati li ọjọ kẹjọ oṣù na, nwọn de iloro Oluwa: bẹ̃ni nwọn fi ọjọ mẹjọ yà ile Oluwa si mimọ́; ati li ọjọ kẹrindilogun oṣù kini na, nwọn pari rẹ̀. |
| 18 |
| Nigbana ni nwọn wọle tọ̀ Hesekiah ọba, nwọn si wipe: Awa ti gbá ile Oluwa mọ́, ati pẹpẹ ẹbọ sisun, pẹlu gbogbo ohun-elo rẹ̀, ati tabili akara-ifihan, pẹlu gbogbo ohun-elo rẹ̀. |
| 19 |
| Pẹlupẹlu gbogbo ohun-elo, ti Ahasi, ọba, ti sọ di alaimọ́ ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, li akokò ijọba rẹ̀, li awa ti pese ti awa si ti yà si mimọ́, si kiyesi i, nwọn mbẹ niwaju pẹpẹ Oluwa. |
| 20 |
| Nigbana ni Hesekiah, ọba, dide ni kutukutu; o si kó awọn olori ilu jọ, o si gòke lọ sinu ile Oluwa. |
| 21 |
| Nwọn si mu akọ-malu meje wá, ati àgbo meje, ati ọdọ-agutan meje, ati obukọ meje fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ fun ijọba na, ati fun ibi mimọ́ na, ati fun Juda. O si paṣẹ fun awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni, lati fi wọn rubọ lori pẹpẹ Oluwa. |
| 22 |
| Bẹ̃ni awọn alufa pa awọn akọ-malu na, nwọn si gba ẹ̀jẹ na, nwọn si fi wọ́n ara pẹpẹ: bẹ̃ gẹgẹ nigbati nwọn pa awọn àgbo, nwọn fi ẹ̀jẹ na wọ́n ara pẹpẹ; nwọn pa awọn ọdọ-agutan pẹlu nwọn si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ara pẹpẹ. |
| 23 |
| Nwọn si mu awọn òbukọ ẹbọ-ẹ̀ṣẹ wá siwaju ọba ati ijọ enia na: nwọn si fi ọwọ wọn le wọn lori. |
| 24 |
| Awọn alufa si pa wọn, nwọn si fi ẹ̀jẹ wọn ṣe ilaja lori pẹpẹ, lati ṣe etutu fun gbogbo Israeli; nitoriti ọba paṣẹ, ki a ṣe ẹbọ sisun ati ẹbọ-ẹ̀ṣẹ fun gbogbo Israeli. |
| 25 |
| O si mu awọn ọmọ Lefi duro ninu ile Oluwa, pẹlu kimbali, pẹlu ohun-elo orin, ati pẹlu duru, gẹgẹ bi aṣẹ Dafidi, ati ti Gadi, ariran ọba, ati Natani, woli, nitori aṣẹ Oluwa ni lati ọwọ awọn woli rẹ̀. |
| 26 |
| Awọn ọmọ Lefi si duro pẹlu ohun-elo orin Dafidi, ati awọn alufa pẹlu ipè. |
| 27 |
| Hesekiah si paṣẹ lati ru ẹbọ sisun lori pẹpẹ na. Nigbati ẹbọ sisun na si bẹ̀rẹ, orin Oluwa bẹ̀rẹ pẹlu ipè ati pẹlu ohun-elo orin Dafidi, ọba Israeli. |
| 28 |
| Gbogbo ijọ enia na si wolẹ sìn, awọn akọrin, kọrin, ati awọn afunpè fun: gbogbo wọnyi si wà bẹ̃ titi ẹbọ sisun na fi pari tan. |
| 29 |
| Nigbati nwọn si ṣe ipari ẹbọ riru, ọba ati gbogbo awọn ti o wà pẹlu rẹ̀ tẹ̀ ara wọn ba, nwọn si sìn. |
| 30 |
| Pẹlupẹlu Hesekiah ọba, ati awọn ijoye paṣẹ fun awọn ọmọ Lefi, lati fi ọ̀rọ Dafidi ati ti Asafu ariran, kọrin iyìn si Oluwa: nwọn si fi inu-didùn kọrin iyìn, nwọn si tẹri wọn ba, nwọn si sìn. |
| 31 |
| Nigbana ni Hesekiah dahùn, o si wipe, Nisisiyi, ọwọ nyin kún fun ẹ̀bun fun Oluwa, ẹ ṣunmọ ihin, ki ẹ si mu ẹbọ ati ọrẹ-ọpẹ wá sinu ile Oluwa. Ijọ ẹnia si mu ẹbọ ati ọrẹ-ọpẹ wá; ati olukuluku ti ọkàn rẹ̀ fẹ, mu ẹbọ sisun wá. |
| 32 |
| Iye ẹbọ sisun, ti ijọ enia mu wá, si jẹ ãdọrin akọ-malu, ati ọgọrun àgbo, ati igba ọdọ-agutan: gbogbo wọnyi si ni fun ẹbọ-sisun si Oluwa. |
| 33 |
| Awọn ohun ìyasi-mimọ́ si jẹ ẹgbẹta malu, ati ẹgbẹdogun agutan. |
| 34 |
| Ṣugbọn awọn alufa kò to, nwọn kò si le họ gbogbo awọn ẹran ẹbọ sisun na: nitorina awọn arakunrin wọn, awọn ọmọ Lefi ràn wọn lọwọ, titi iṣẹ na fi pari, ati titi awọn alufa iyokù fi yà ara wọn si mimọ́: nitori awọn ọmọ Lefi ṣe olõtọ li ọkàn jù awọn alufa lọ lati yà ara wọn si mimọ́. |
| 35 |
| Ati pẹlu, awọn ẹbọ sisun papọju, pẹlu ọra ẹbọ-alafia, pẹlu ẹbọ ohun-mimu fun ẹbọ sisun. Bẹ̃li a si to iṣẹ́-ìsin ile Oluwa li ẹsẹsẹ. |
| 36 |
| Hesekiah si yọ̀, ati gbogbo enia pe, Ọlọrun ti mura awọn enia na silẹ: nitori li ojiji li a ṣe nkan na. |
|
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/2chronicles/029.mp3
36
29