|
| 1 |
|
| JOBU si dahùn o si wipe, |
|
| 2 |
|
| Kò si ani-ani nibẹ̀, ṣugbọn ẹnyin li awọn enia na, ọgbọ́n yio si kú pẹlu nyin. |
|
| 3 |
|
| Ṣugbọn emi ni iyè ninu gẹgẹ bi ẹnyin: emi kì iṣe ọmọ-ẹhin nyin: ani, tani kò mọ̀ nkan bi iru wọnyi? |
|
| 4 |
|
| Emi dabi ẹniti a nfi ṣe ẹlẹya lọdọ aladugbo rẹ̀, ti o kepe Ọlọrun, ti o si da a lohùn: a nfi olõtọ ẹni-iduro-ṣinṣin rẹrin ẹlẹyà. |
|
| 5 |
|
| Ẹgan ni ẹni-òtoṣi, ti ẹsẹ rẹ̀ mura tan lati yọ́ ninu ìro ẹniti ara rọ̀. |
|
| 6 |
|
| Agọ awọn igara ngberú, awọn ti o si nmu Ọlọrun binu wà lailewu, awọn ẹniti o si gbá oriṣa mu li ọwọ wọn. |
|
| 7 |
|
| Ṣugbọn nisisiyi, bi awọn ẹranko lere, nwọn o kọ́ ọ li ẹkọ́, ati ẹiyẹ oju ọrun, nwọn o si sọ fun ọ. |
|
| 8 |
|
| Tabi, ba ilẹ aiye sọ̀rọ, yio si kọ́ ọ, awọn ẹja inu okun yio si sọ fun ọ. |
|
| 9 |
|
| Tani kò mọ̀ ninu gbogbo wọnyi pe, ọwọ Oluwa li o ṣe nkan yi? |
|
| 10 |
|
| Lọwọ ẹniti ẹmi ohun alãye gbogbo gbé wà, ati ẹmi gbogbo araiye. |
|
| 11 |
|
| Eti ki idán ọ̀rọ wò bi? tabi adùn ẹnu ki isi tọ onjẹ rẹ̀ wò? |
|
| 12 |
|
| Awọn arugbo li ọgbọ́n wà fun, ati ninu gigùn ọjọ li oye. |
|
| 13 |
|
| Pẹlu rẹ̀ (Ọlọrun) li ọgbọ́n ati agbarà, on ni ìmọ ati oye, |
|
| 14 |
|
| Kiyesi i, o biwó, a kò si le igbe ró mọ́, o se enia mọ́, kò si sí iṣisilẹ̀ kan. |
|
| 15 |
|
| Kiyesi i, o da awọn omi duro, nwọn si gbẹ, o si rán wọn jade, nwọn si ṣẹ bo ilẹ aiye yipo. |
|
| 16 |
|
| Pẹlu rẹ̀ li agbara ati ọgbọ́n, ẹniti nṣìna ati ẹniti imu ni ṣìna tirẹ̀ ni nwọn iṣe. |
|
| 17 |
|
| O mu awọn igbimọ̀ lọ nihoho, a si sọ awọn onidajọ di wère. |
|
| 18 |
|
| O tu ide ọba, o si fi àmure gbà wọn li ọ̀ja. |
|
| 19 |
|
| O mu awọn alufa lọ nihoho, o si tẹ ori awọn alagbara bá. |
|
| 20 |
|
| O mu ọ̀rọ-ẹnu ẹni-igbẹkẹle kuro, o si ra awọn àgbàgbà ni iye. |
|
| 21 |
|
| O bù ẹ̀gan lu awọn ọmọ-alade, o si tú àmure awọn alagbara. |
|
| 22 |
|
| O hudi ohun ti o sigbẹ jade lati inu òkunkun wá, o si mu ojiji ikú jade wá sinu imọlẹ̀. |
|
| 23 |
|
| On a mu orilẹ-ède bi si i, a si run wọn, on a sọ orilẹ-ède di nla, a si tun ṣẹ́ wọn kù. |
|
| 24 |
|
| On a gbà aiya olú awọn enia aiye, a si ma mu wọn wọ́ kakiri ninu iju nibiti ọ̀na kò si. |
|
| 25 |
|
| Nwọn a ma fi ọwọ ta ilẹ ninu òkunkun laisi imọlẹ, on a si ma mu wọn tàse irin bi ọmuti. |
|
|
|
|