Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| EMI mi bajẹ, ọjọ mi parun, isa-okú duro dè mi. |
| 2 |
| Nitõtọ! awọn ẹlẹya wà lọdọ mi, oju mi si tẹmọ́ imunibinu wọn. |
| 3 |
| Njẹ nisisiyi, fi lelẹ! yàn onigbọwọ fun mi lọdọ rẹ; tani oluwa rẹ̀ ti yio ba mi so ọwọ pọ̀? |
| 4 |
| Nitoripe iwọ ti sé wọn laiya kuro ninu oye, nitorina iwọ kì yio gbé wọn leke. |
| 5 |
| Ẹniti o fi awọn ọrẹ hàn fun igára, on ni oju awọn ọmọ rẹ̀ yio mu ofo. |
| 6 |
| O si sọ mi di ẹni-owe fun awọn enia, niwaju wọn ni mo dabi ẹni itutọ́ si li oju. |
| 7 |
| Oju mi ṣú baibai pẹlu nitori ibinujẹ, gbogbo ẹ̀ya ara mi si dabi ojiji. |
| 8 |
| Awọn olododo yio yanu si eyi, ẹni alaiṣẹ̀ si binu si awọn àgabagebe. |
| 9 |
| Olododo pẹlu yio di ọ̀na rẹ̀ mu, ati ọlọwọ mimọ́ yio ma lera siwaju. |
| 10 |
| Ṣugbọn bi o ṣe ti gbogbo nyin, ẹ yipada, ki ẹ si tun bọ̀ nisisiyi, emi kò le ri ọlọgbón kan ninu nyin. |
| 11 |
| Ọjọ ti emi ti kọja, iro mi ti fà já, ani iro inu mi. |
| 12 |
| A sọ oru di ọ̀san; nwọn ni, imọlẹ sunmọ ibiti òkunkun de. |
| 13 |
| Bi mo tilẹ ni ireti, ipo-okú ni ile mi, mo ti tẹ bùsun mi sinu òkunkun. |
| 14 |
| Emi ti wi fun idibajẹ pe, Iwọ ni baba mi, ati fun kòkoro pe, Iwọ ni iya mi ati arabinrin mi. |
| 15 |
| Ireti mi ha dà nisisiyi? bi o ṣe ti ireti mi ni, tani yio ri i? |
| 16 |
| O sọkalẹ lọ sinu ọgbun ipo-okú, nigbati a jumọ simi pọ̀ ninu erupẹ ilẹ. |
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/job/017.mp3
42
17