|
| 1 |
|
| NIGBANA ni Jobu dahùn o si wipe, |
|
| 2 |
|
| Yio ti pẹ to ti ẹnyin o fi ma bà mi ninu jẹ, ti ẹnyin o fi ma fi ọ̀rọ kun mi ni ìjanja? |
|
| 3 |
|
| Igba mẹwa li ẹnyin ti ngàn mi, oju kò tì nyin ti ẹ fi jẹ mi niya. |
|
| 4 |
|
| Ki a fi sí bẹ̃ pe, mo ṣìna nitõtọ, ìṣina mi wà lara emi tikarami. |
|
| 5 |
|
| Bi o tilẹ ṣepe ẹnyin o ṣogo si mi lori nitõtọ, ti ẹ o si ma fi ẹ̀gan mi gun mi loju. |
|
| 6 |
|
| Ki ẹ mọ̀ nisisiyi pe: Ọlọrun li o bì mi ṣubu, o si nà àwọn rẹ̀ yi mi ka. |
|
| 7 |
|
| Kiyesi i, emi nkigbe pe, Ọwọ́ alagbara! ṣugbọn a kò gbọ́ ti emi; mo kigbe soke, bẹ̃ni kò si idajọ. |
|
| 8 |
|
| O sọ̀gba di ọ̀na mi ti emi kò le kọja, o si mu òkunkun ṣú si ipa ọ̀na mi: |
|
| 9 |
|
| O ti bọ́ ogo mi, o si ṣi ade kuro li ori mi. |
|
| 10 |
|
| O ti bà mi jẹ ni iha gbogbo, ẹmi si pin; ireti mi li a o si fatu bi igi: |
|
| 11 |
|
| O si tinabọ ibinu rẹ̀ si mi, o si kà mi si bi ọkan ninu awọn ọta rẹ̀. |
|
| 12 |
|
| Ẹgbẹ́ ogun rẹ̀ si dàpọ si mi, nwọn si tẹgun si mi, nwọn si dó yi agọ mi ka. |
|
| 13 |
|
| O mu awọn arakunrin mi jina si mi rére, ati awọn ojulumọ mi di ajeji si mi nitõtọ. |
|
| 14 |
|
| Awọn ajọbi mi fà sẹhin, awọn afaramọ́ ọrẹ mi si di onigbagbe mi. |
|
| 15 |
|
| Awọn ara inu ile mi ati awọn ọmọbinrin iranṣẹ mi kà mi si ajeji, emi jasi ajeji enia li oju wọn. |
|
| 16 |
|
| Mo pè iranṣẹ mi, on kò si da mi lohùn, mo fi ẹnu mi bẹ̀ ẹ. |
|
| 17 |
|
| Ẹmi mi sú aya mi, ati õrùn mi sú awọn ọmọ inu iya mi. |
|
| 18 |
|
| Ani awọn ọmọde fi mi ṣẹsin: mo dide, nwọn si sọ̀rọ ẹ̀gan si mi. |
|
| 19 |
|
| Gbogbo awọn ọrẹ idimọpọ mi korira mi, awọn olufẹ mi si kẹ̀hinda mi. |
|
| 20 |
|
| Egungun mi lẹ mọ́ awọ ara mi ati mọ́ ẹran ara mi, mo si bọ́ pẹlu awọ ehin mi. |
|
| 21 |
|
| Ẹ ṣãnu fun mi, ẹ ṣãnu fun mi, ẹnyin ọrẹ mi, nitori ọwọ Ọlọrun ti bà mi. |
|
| 22 |
|
| Nitori kili ẹnyin ṣe lepa mi bi Ọlọrun, ti ẹran ara mi kò tẹ́ nyin lọrùn! |
|
| 23 |
|
| A! Ibaṣepe a le kọwe ọ̀rọ mi nisisiyi, ibaṣepe a le dà a sinu iwe! |
|
| 24 |
|
| Ki a fi kalamu irin ati ti ojé kọ́ wọn sinu apata fun lailai. |
|
| 25 |
|
| Ati emi, emi mọ̀ pe Oludande mi mbẹ li ãyè, ati pe on bi Ẹni-ikẹhin ni yio dide soke lori erupẹ ilẹ. |
|
| 26 |
|
| Ati lẹhin igba awọ ara mi, ti a ti ke e kuro bi iru eyi, ati laili ẹran ara mi li emi o ri Ọlọrun, |
|
| 27 |
|
| Ẹniti emi o ri fun ara mi, ti oju mi o si wò, kì si iṣe ti ẹlomiran; ọkàn mi si dáku ni inu mi. |
|
| 28 |
|
| Bi ẹnyin ba wipe, Awa o ti lepa rẹ̀ to! ati pe, gbongbo ọ̀rọ na li a sa ri li ọwọ mi, |
|
| 29 |
|
| Ki ẹnyin ki o bẹ̀ru idà; nitoripe ibinu ni imu ijiya idà wá: ki ẹnyin ki o lè imọ̀ pe idajọ kan mbẹ. |
|
|
|
|