×

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMY) 2014

Jobu 2

1
Ó sì tún di ọjọ́ kan nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run wá síwájú OLÚWA, Sàtánì sì wá pẹ̀lú wọn láti pe níwájú OLÚWA.
2
OLÚWA sì bi Sàtánì pé, Níbo ni ìwọ ti wá? Sàtánì sì dá OLÚWA lóhùn pé, “Láti lọ síwá sẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé àti ní ìrìnkèrindò nínú rẹ̀.”
3
OLÚWA sì wí fún Sàtánì pé, “Ìwọ ha kíyèsí Jóòbù ìránṣẹ́ mi, pé, kò sí èkejì rẹ̀ ní ayé, ọkùnrin tí ń ṣe olóòótọ́ tí ó sì dúró sinsin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì kóríra ìwà búburú, bẹ́ẹ̀ ni ó sì di ìwà òtítọ́ rẹ̀ mu ṣinṣin, bí ìwọ tilẹ̀ ti dẹ mí sí i láti run-ún láìnídìí.”
4
Sàtánì sì dá OLÚWA lóhùn wí pé, “Awọ fún awọ; àní ohun gbogbo tí ènìyàn ní, òun ni yóò fi ra ẹ̀mí rẹ̀.
5
Ṣùgbọ́n nawọ́ rẹ nísinsìn yìí, kí ó tọ́ egungun rẹ̀ àti ara rẹ̀, bí kì yóò sì bọ́hùn ní ojú rẹ.”
6
OLÚWA sì wí fún Sàtánì pé, “Wò ó, Ó ń bẹ ní ìkàwọ́ rẹ, ṣùgbọ́n dá ẹ̀mí rẹ̀ sí.”
7
Bẹ́ẹ̀ ni Sàtánì jáde lọ kúrò níwájú OLÚWA, ó sì sọ Jóòbù ní oówo kíkan kíkan láti àtẹ́lẹṣẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀
8
Ó sì mú àpáàdì, ó fi ń ha ara rẹ̀, ó sì jókòó nínú eérú.
9
Nígbà náà ni aya rẹ̀ wí fún-un pé, “Ìwọ di ìwà òtítọ́ mú síbẹ̀! Bú Ọlọ́run, kí ó sì kú!”
10
Ṣùgbọ́n ó dá a lóhùn pé, “Ìwọ sọ̀rọ̀ bí ọ̀kan lára àwọn obìnrin aláìmọ́ye ti í sọ̀rọ̀; há bà! Àwa yóò ha gba ire lọ́wọ́ Ọlọ́run, kí a má sì gba ibi?” Nínú gbogbo èyí, Jóòbù kò fi ètè rẹ̀ ṣẹ̀.
11
Nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́ta gbúròó gbogbo ibi tí ó bá a, wọ́n wá, olúkúlùkù láti ibùjókòó rẹ̀; Élífásì, ara Témà àti Bílídádì, ara Ṣúà, àti Sófárì, ará Náámù: nítorí pé wọ́n ti dájọ́ ìpàdé pọ̀ láti bá a sọ̀fọ̀ àti láti sìpẹ̀ fún un.
12
Nígbà tí wọ́n gbójú wọn wò ní òkèrè réré, tí wọ́n kò sì mọ̀ ọ́n, wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sọkún: olúkúlùkù sì fa àṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya, wọ́n sì ku erùpẹ̀ sí ojú ọ̀run, wọ́n sì tẹ́ orí gbà á.
13
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n jòkòó tì í ní inú erùpẹ̀ ní ọjọ́ méje ti ọ̀sán ti òru, ẹnikẹ́ni kò sì bá a dá ọ̀rọ̀ kan sọ nítorí tí wọ́n ti rí i pé ìbànújẹ́ rẹ̀ pọ̀ gidigidi.
Yoruba Bible (BMY) 2014
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® worldwide
:
Fipamọ Awọn akọsilẹ