|
| 1 |
|
| NIGBANA ni Elifasi, ara Tema, dahùn wipe, |
|
| 2 |
|
| Enia le iṣe rere fun Ọlọrun, bi ọlọgbọ́n ti iṣe rere fun ara rẹ̀. |
|
| 3 |
|
| Ohun ayọ̀ ha ni fun Olodumare pe, olododo ni iwọ? tabi ere ni fun u, ti iwọ mu ọ̀na rẹ pé? |
|
| 4 |
|
| Yio ha ba ọ wi bi nitori ìbẹru Ọlọrun rẹ, yio ha ba ọ lọ sinu idajọ bi? |
|
| 5 |
|
| Iwa-buburu rẹ kò ha tobi, ati ẹ̀ṣẹ rẹ lainiye? |
|
| 6 |
|
| Nitõtọ iwọ gbà ohun ẹri li ọwọ arakunrin rẹ lainidi, iwọ si tú onihoho li aṣọ wọn. |
|
| 7 |
|
| Iwọ kò fi omi fun alãrẹ mu, iwọ si hawọ onjẹ fun ẹniti ebi npa. |
|
| 8 |
|
| Bi o ṣe ti alagbara nì ni, on li o ni aiye, ọlọla si tẹdo sinu rẹ̀. |
|
| 9 |
|
| Iwọ ti rán awọn opó pada lọ li ọwọ ofo, apa awọn ọmọ alainibaba ti di ṣiṣẹ́. |
|
| 10 |
|
| Nitorina ni idẹkun ṣe yi ọ kakiri, ati ìbẹru ojiji nyọ ọ lẹnu. |
|
| 11 |
|
| Tabi iwọ kò ha ri okunkun, ati ọ̀pọlọpọ omi ti o bò ọ mọlẹ? |
|
| 12 |
|
| Ọlọrun kò ha jẹ Ẹni giga ọrun? sa wò ori awọn ìrawọ̀ bi nwọn ti ga tó! |
|
| 13 |
|
| Iwọ si wipe, Ọlọrun ti ṣe mọ̀, on ha le iṣe idajọ lati inu awọsanma dudu wá bi? |
|
| 14 |
|
| Awọsanma ti o nipọn ni ibora fun u, ti kò fi le riran; o si rin ninu ayika ọrun. |
|
| 15 |
|
| Iwọ fẹ rìn ipa-ọ̀na igbani ti awọn enia buburu ti rìn. |
|
| 16 |
|
| Ti a ke lulẹ kuro ninu aiye laipé ọjọ wọn, ipilẹ wọn ti de bi odò ṣiṣàn. |
|
| 17 |
|
| Awọn ẹniti o wi fun Ọlọrun pe, Lọ kuro lọdọ wa! Kini Olodumare yio ṣe fun wọn. |
|
| 18 |
|
| Sibẹ o fi ohun rere kún ile wọn! ṣugbọn ìmọ enia-buburu jìna si mi! |
|
| 19 |
|
| Awọn olododo ri i, nwọn si yọ̀, awọn alailẹ̀ṣẹ si fi wọn rẹrin ẹlẹya pe: |
|
| 20 |
|
| Lotitọ awọn ọta wa ni a ke kuro, iná yio si jó iyokù wọn run. |
|
| 21 |
|
| Fa ara rẹ sunmọ Ọlọrun, iwọ o si ri alafia; nipa eyinì rere yio wá ba ọ. |
|
| 22 |
|
| Emi bẹ̀ ọ, gba ofin lati ẹnu rẹ̀ wá, ki o si tò ọ̀rọ rẹ̀ si aiya rẹ. |
|
| 23 |
|
| Bi iwọ ba yipada sọdọ Olodumare, a si gbe ọ ró, bi iwọ ba si mu ẹ̀ṣẹ jina rére kuro ninu agọ rẹ. |
|
| 24 |
|
| Ti iwọ ba tẹ wura daradara silẹ lori erupẹ ati wura ófiri labẹ okuta odò. |
|
| 25 |
|
| Nigbana ni Olodumare yio jẹ iṣura rẹ, ani yio si jẹ fadaka fun ọ ni ọ̀pọlọpọ. |
|
| 26 |
|
| Lotitọ nigbana ni iwọ o ni inu didùn ninu Olodumare, iwọ o si gbe oju rẹ soke sọdọ Ọlọrun. |
|
| 27 |
|
| Bi iwọ ba gbadura rẹ sọdọ rẹ̀, yio si gbọ́ tirẹ, iwọ o si san ẹ̀jẹ́ rẹ. |
|
| 28 |
|
| Iwọ si gbimọ ohun kan pẹlu, yio si fi idi mulẹ fun ọ; imọlẹ yio si mọ́ sipa ọ̀na rẹ. |
|
| 29 |
|
| Nigbati ipa-ọ̀na rẹ ba lọ sisalẹ, nigbana ni iwọ o wipe, Igbesoke mbẹ! Ọlọrun yio si gba onirẹlẹ là! |
|
| 30 |
|
| Yio gba ẹniti kì iṣe alaijẹbi là, a o si gbà a nipa mimọ́ ọwọ rẹ. |
|
|
|
|