×

Bibeli Mimọ Bible 2012

Jobu 27

1
PẸLUPẸLU Jobu si tun sọ kún ọ̀rọ owe rẹ̀ o si wipe,
2
Bi Ọlọrun ti mbẹ ẹniti o gba idajọ mi lọ, ati Olodumare ti o bà mi li ọkàn jẹ.
3
Niwọn igba ti ẹmi mi mbẹ ninu mi, ati ti ẹmi Ọlọrun mbẹ ni iho imú mi.
4
Ete mi kì yio sọ̀rọ eké, bẹ̃li ahọn mi kì yio sọ̀rọ ẹ̀tan.
5
Ki a ma ri pe emi ndá nyin li are, titi emi o fi kú emi kì yio ṣi ìwa otitọ mi kuro lọdọ mi.
6
Ododo mi li emi dimú ṣinṣin, emi kì yio si jọwọ rẹ̀ lọwọ; aiya mi kì yio si gan ọjọ kan ninu ọjọ aiye mi.
7
Ki ọta mi ki o dàbi enia buburu, ati ẹniti ndide si mi ki o dàbi ẹni alaiṣododo.
8
Nitoripe kini ireti àgabagebe, nigbati Ọlọrun ba ke ẹmi rẹ̀ kuro, nigbati o si fà a jade.
9
Ọlọrun yio ha gbọ́ adura rẹ̀, nigbati ipọnju ba de si i?
10
On ha le ni inu-didùn si Olodumare, on ha le ma kepe Ọlọrun nigbagbogbo?
11
Emi o kọ́ nyin li ẹkọ́ niti ọwọ Ọlọrun: eyi ti mbẹ lọdọ Olodumare li emi kì yio fi pamọ.
12
Kiyesi i, gbogbo nyin li o ti ri i, nitori kili ẹnyin ṣe jasi asan pọ̀ bẹ̃?
13
Eyi ni ipín enia buburu lọdọ Ọlọrun, ati ogún awọn aninilara, ti nwọn o gbà lọwọ Olodumare.
14
Bi awọn ọmọ rẹ̀ ba di pupọ̀, fun idà ni, awọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ kì yio yo fun onjẹ.
15
Awọn ti o kù ninu tirẹ̀ li a o sinkú ninu ajakalẹ àrun: awọn opó rẹ̀ kì yio si sọkún.
16
Bi o tilẹ kó fàdaka jọ bi erupẹ, ti o si da aṣọ jọ bi amọ̀.
17
Ki o ma dá a, ṣugbọn awọn olõtọ ni yio lò o; awọn alaiṣẹ̀ ni yio si pin fadaka na.
18
On kọ́ ile rẹ̀ bi kòkoro aṣọ, ati bi agọbukà ti oluṣọ pa.
19
Ọlọrọ̀ yio dubulẹ, ṣugbọn on kì o tùn ṣe bẹ̃ mọ́, o ṣiju rẹ̀, on kò sì si.
20
Ẹ̀ru nla bà a bi omi ṣiṣan, ẹ̀fufu nla ji i gbe lọ li oru.
21
Ẹfufu ila-õrùn gbe e lọ, on si lọ; ati bi iji nla o si fà a kuro ni ipo rẹ̀.
22
Nitoripe Olodumare yio kọlù u, kì o sì dasi; on iba yọ̀ lati sá kuro li ọwọ rẹ̀.
23
Awọn enia yio si ṣapẹ si i lori, nwọn o si ṣe ṣiọ si i kuro ni ipò rẹ̀.
Yoruba Bible 2012
Yoruba Bible Crowther Version The Bible Society of Nigeria, 2012
:
Fipamọ Awọn akọsilẹ