|
| 1 |
|
| NITOTỌ ipa-ilẹ fàdaka mbẹ, ati ibi ti nwọn a ma idà wura. |
|
| 2 |
|
| Ninu ilẹ li a gbe nwà irin, bàba li a si ndà lati inu okuta wá. |
|
| 3 |
|
| Enia li o pari òkunkun, o si ṣe awari okuta òkunkun ati ti inu ojiji ikú si iha gbogbo. |
|
| 4 |
|
| Nwọn wá iho ilẹ ti o jìn si awọn ti o ngbe oke, awọn ti ẹsẹ enia gbagbe nwọn rọ si isalẹ, nwọn rọ si isalẹ jina si awọn enia. |
|
| 5 |
|
| Bi o ṣe ti ilẹ ni, ninu rẹ̀ ni onjẹ ti ijade wá, ati ohun ti o wà nisalẹ li o yi soke bi ẹnipe iná. |
|
| 6 |
|
| Okuta ibẹ ni ibi okuta Safiri, o si ni erupẹ wura. |
|
| 7 |
|
| Ipa ọ̀na na ni ẹiyẹ kò mọ̀, ati oju gunugun kò ri i ri. |
|
| 8 |
|
| Awọn ọmọ kiniun kò rin ibẹ rí, bẹ̃ni kiniun ti nké ramuramu kò kọja nibẹ rí. |
|
| 9 |
|
| O fi ọwọ rẹ̀ le akọ apata, o yi oke-nla po lati idi rẹ̀ wá. |
|
| 10 |
|
| O si la ipa-odò ṣiṣàn ninu apata, oju rẹ̀ si ri ohun iyebiye gbogbo. |
|
| 11 |
|
| O si sé iṣàn odò ki o má ṣe kún akunya, o si mu ohun ti o lumọ hàn jade wá si imọlẹ. |
|
| 12 |
|
| Ṣugbọn nibo li a o gbe wá ọgbọ́n ri, nibo si ni ibi oye? |
|
| 13 |
|
| Enia kò mọ̀ iye rẹ̀, bẹ̃li a kò le iri i ni ilẹ awọn alãyè. |
|
| 14 |
|
| Ọgbun wipe, kò si ninu mi, omi-okun si wipe, kò si ninu mi. |
|
| 15 |
|
| A kò le fi wura rà a, bẹ̃li a kò le ifi òṣuwọn wọ̀n fadaka ni iye rẹ̀. |
|
| 16 |
|
| A kò le fi wura Ofiri diyele e, pẹlu okuta oniksi iyebiye, ati okuta Safiri. |
|
| 17 |
|
| Wura ati okuta kristali kò to ẹgbẹ́ rẹ̀, bẹ̃li a kò le fi ohun èlo wura ṣe paṣiparọ rẹ̀. |
|
| 18 |
|
| A kò le idarukọ iyun tabi okuta perli; iye ọgbọ́n si jù okuta rubi lọ. |
|
| 19 |
|
| Okuta topasi ti Etiopia kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀, bẹ̃li a kò le ifi wura daradara diye le e. |
|
| 20 |
|
| Nibo ha li ọgbọn ti jade wá; tabi nibo ni ibi oye? |
|
| 21 |
|
| A ri pe, o lumọ kuro li oju awọn alãyè gbogbo, o si fara sin fun ẹiyẹ oju ọrun. |
|
| 22 |
|
| Ibi iparun (Abaddoni) ati ikú wipe, Awa ti fi etí wa gburo rẹ̀. |
|
| 23 |
|
| Ọlọrun li o moye ipa ọ̀na rẹ̀, o si mọ̀ ipo rẹ̀, |
|
| 24 |
|
| Nitoripe o woye de opin aiye, o si ri gbogbo isalẹ ọrun. |
|
| 25 |
|
| Lati dà òṣuwọn fun afẹfẹ, o si fi òṣuwọn wọ̀n omiyomi. |
|
| 26 |
|
| Nigbati o paṣẹ fun òjo, ti o si la ọ̀na fun mànamana ãrá: |
|
| 27 |
|
| Nigbana li o ri i, o si sọ ọ jade, o pèse rẹ̀ silẹ, ani o si wadi rẹ̀ ri. |
|
| 28 |
|
| Ati fun enia li o wipe, kiyesi i; Ẹru Oluwa, eyi li ọgbọ́n, ati lati jade kuro ninu ìwa-buburu eyi li oye! |
|
|
|
|