|
| 1 |
|
| EMI ti bá oju mi da majẹmu, njẹ emi o ha ṣe tẹjumọ wundia? |
|
| 2 |
|
| Nitoripe kini ipin Ọlọrun lati ọrun wá, tabi kini ogún Olodumare lati oke ọrun wá? |
|
| 3 |
|
| Kò ṣepe awọn enia buburu ni iparun wà fun, ati ìṣẹniṣẹ fun awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ? |
|
| 4 |
|
| On kò ha ri ipa-ọ̀na mi, on kò ha si ka gbogbo iṣiṣe mi? |
|
| 5 |
|
| Bi o ba ṣepe emi ba fi aiṣotitọ rìn, tabi ti ẹsẹ mi si yara si ẹ̀tan. |
|
| 6 |
|
| Ki a diwọn mi ninu iwọ̀n ododo, ki Ọlọrun le imọ̀ iduroṣinṣin mi. |
|
| 7 |
|
| Bi ẹsẹ mi ba yà kuro loju ọ̀na, ti aiya mi si tẹ̀le ipa oju mi, bi àbawọn kan ba si lẹmọ́ mi li ọwọ. |
|
| 8 |
|
| Njẹ ki emi ki o gbìn ki ẹlomiran ki o si mu u jẹ, ani ki a fà iru-ọmọ mi tu. |
|
| 9 |
|
| Bi aiya mi ba di fifa sipasẹ obinrin kan, tabi bi mo ba lọ ibadeni li ẹnu-ọ̀na ile aladugbo mi, |
|
| 10 |
|
| Njẹ ki aya mi ki o lọ ọlọ fun ẹlomiran, ki awọn ẹlomiran ki o tẹ̀ ara wọn li ara rẹ̀. |
|
| 11 |
|
| Nitoripe ẹ̀ṣẹ buburu li eyi; ani ẹ̀ṣẹ ìṣẹniṣẹ ni lọdọ awọn onidajọ. |
|
| 12 |
|
| Nitoripe iná ni eyi ti o jo de iparun, ti iba si fà gbongbo ohun ibisi mi gbogbo tu. |
|
| 13 |
|
| Bi mo ba si ṣe aikà ọ̀ran iranṣẹkunrin mi tabi iranṣẹbinrin mi si, nigbati nwọn ba mba mi jà; |
|
| 14 |
|
| Kili emi o ha ṣe nigbati Ọlọrun ba dide; nigbati o ba si ṣe ibẹwo, ohùn kili emi o dá? |
|
| 15 |
|
| Ẹniti o dá mi ni inu kọ li o da a? ẹnikanna ki o mọ wa ni inu? |
|
| 16 |
|
| Bi mo ba fà ọwọ sẹhin fun ifẹ-inu talaka, tabi bi mo ba si mu oju opó mofo; |
|
| 17 |
|
| Tabi ti mo ba nikan bu òkele mi jẹ, ti alainibaba kò jẹ ninu rẹ̀; |
|
| 18 |
|
| Nitoripe lati igba ewe mi wá li a ti tọ́ ọ dàgba pẹlu mi bi ẹnipe baba, emi si nṣe itọju rẹ̀ (opó) lati inu iya mi wá. |
|
| 19 |
|
| Bi emi ba ri olupọnju laini aṣọ, tabi talaka kan laini ibora; |
|
| 20 |
|
| Bi ẹgbẹ rẹ̀ kò ba sure fun mi, tabi bi ara rẹ̀ kò si gbona nipasẹ irun agutan mi. |
|
| 21 |
|
| Bi mo ba si gbe ọwọ mi soke si alainibaba, nitoripe mo ri iranlọwọ mi li ẹnu-bode, |
|
| 22 |
|
| Njẹ ki apá mi ki o wọ́n kuro li ọkọ́ ejika rẹ̀, ki apá mi ki o si ṣẹ́ lati egungun rẹ̀ wá. |
|
| 23 |
|
| Nitoripe iparun lati ọdọ Ọlọrun wá ni ẹ̀ru-nla fun mi, ati nitori Ọlanla rẹ̀ emi kò le iduro. |
|
| 24 |
|
| Bi o ba ṣepe mo fi wura ṣe igbẹkẹle mi, tabi bi mo ba wi fun wura didara pe, iwọ ni igbẹkẹle mi; |
|
| 25 |
|
| Bi mo ba yọ̀ nitori ọrọ̀ mi pọ̀, ati nitori ọwọ mi dẹ̀ lọpọlọpọ; |
|
| 26 |
|
| Bi mo ba bojuwo õrùn nigbati nràn, tabi òṣupa ti nrin ninu itan-imọlẹ, |
|
| 27 |
|
| Ti aiya mi si di titan, lati fi ẹnu mi kò ọwọ mi: |
|
| 28 |
|
| Eyi pẹlu li ẹ̀ṣẹ ìṣẹniṣẹ lọdọ awọn onidajọ, nitoripe emi iba sẹ́ Ọlọrun ti o wà loke. |
|
| 29 |
|
| Bi o ba ṣepe mo yọ̀ si iparun ẹniti o korira mi, tabi bi mo ba si gbera soke, nigbati ibi bá a. |
|
| 30 |
|
| Bẹ̃li emi kò si jẹ ki ẹnu mi ki o ṣẹ̀ nipa fifẹ egún si ọkàn rẹ̀. |
|
| 31 |
|
| Bi awọn enia inu agọ mi kò ba le wipe, Tali o le ri ẹniti agbo-ẹran rẹ̀ kò tẹlọrùn? |
|
| 32 |
|
| Alejo kò wọ̀ ni igboro ri, emi ṣi ilẹkun mi silẹ fun èro. |
|
| 33 |
|
| Bi mo ba bò irekọja mi mọlẹ bi Adamu, ni pipa ẹbi mi mọ́ li aiya mi: |
|
| 34 |
|
| Ọ̀pọlọpọ enia ni mo ha bẹ̀ru bi, tabi ẹ̀gan awọn idile ni mba mi li ẹ̀ru? ti mo fi pa ẹnu mọ́, ti emi kò si fi jade sode? |
|
| 35 |
|
| Ibaṣepe ẹnikan le gbọ́ ti emi! kiyesi i, àmi mi! ki Olodumare ki o da mi lohùn! ki emi ki o si ri iwe na ti ọta mi ti kọ! |
|
| 36 |
|
| Nitõtọ emi iba gbe e le ejika mi, emi iba si dì i bi ade mọ́ ori mi. |
|
| 37 |
|
| Emi iba si sọ iye ìṣisẹ mi fun u, bi ọmọ-alade li emi iba sunmọ ọdọ rẹ̀. |
|
| 38 |
|
| Bi ilẹ mi ba si ke fi mi sùn, tabi ti aporo rẹ̀ pẹlu si sọkun, |
|
| 39 |
|
| Bi mo ba jẹ eso oko mi lainawo si i, tabi ti mo si mu ọkàn oluwa rẹ̀ fò lọ, |
|
| 40 |
|
| Ki ẹgun òṣuṣu ki o hù nipo alikama, ati wèpe nipo ọka-bàba. (Ọ̀rọ Jobu pari.) |
|
|
|
|