|
| 1 |
|
| BẸ̃NI awọn ọkunrin mẹtẹta wọnyi dakẹ lati da Jobu lohùn, nitori o ṣe olododo loju ara rẹ̀. |
|
| 2 |
|
| Nigbana ni inu bi Elihu, ọmọ Barakeli, ara Busi, lati ibatan idile Ramu; o binu si Jobu, nitoriti o da ara rẹ̀ lare kàka ki o da Ọlọrun lare. |
|
| 3 |
|
| Inu rẹ̀ si bi si awọn ọ̀rẹ rẹ̀ mẹtẹta, nitoriti nwọn kò ni idahùn, bẹ̃ni nwọn dá Jobu lẹbi. |
|
| 4 |
|
| Njẹ Elihu ti duro titi Jobu fi sọ̀rọ tan, nitoriti awọn wọnyi dàgba jù on lọ ni iye ọjọ. |
|
| 5 |
|
| Nigbati Elihu ri pe idahùn ọ̀rọ kò si li ẹnu awọn ọkunrin mẹtẹta wọnyi, nigbana ni o binu. |
|
| 6 |
|
| Elihu, ọmọ Barakeli, ara Busi, dahùn o si wipe, Ọmọde li emi, àgba si li ẹnyin; njẹ nitorina ni mo duro, mo si mbẹ̀ru lati fi ìmọ mi hàn nyin. |
|
| 7 |
|
| Emi wipe, ọjọ-jọjọ ni iba sọ̀rọ, ati ọ̀pọlọpọ ọdun ni iba ma kọ́ni li ọgbọ́n. |
|
| 8 |
|
| Ṣugbọn ẹmi kan ni o wà ninu enia, ati imisi Olodumare ni isi ma fun wọn li oye. |
|
| 9 |
|
| Enia nlanla kì iṣe ọlọgbọ́n, bẹ̃ni awọn àgba li oye idajọ kò ye. |
|
| 10 |
|
| Nitorina li emi ṣe wipe, ẹ dẹtisilẹ si mi, emi pẹlu yio fi ìmọ mi hàn. |
|
| 11 |
|
| Kiyesi i, emi ti duro de ọ̀rọ nyin, emi fetisi aroye nyin, nigbati ẹnyin nwá ọ̀rọ ti ẹnyin o sọ. |
|
| 12 |
|
| Ani mo fiyesi nyin tinutinu, si kiyesi i, kò si ẹnikan ninu nyin ti o le já Jobu li irọ́, tabi ti o lè ida a lohùn ọ̀rọ rẹ̀! |
|
| 13 |
|
| Ki ẹnyin ki o má ba wipe, awa wá ọgbọ́n li awari: Ọlọrun li o lè bi i ṣubu, kì iṣe enia. |
|
| 14 |
|
| Bi on kò ti sọ̀rọ si mi, bẹ̃li emi kì yio fi ọ̀rọ nyin da a lohùn. |
|
| 15 |
|
| Ẹnu si yà wọn, nwọn kò si dahùn mọ́, nwọn ṣiwọ ọ̀rọ isọ. |
|
| 16 |
|
| Mo si reti, nitoriti nwọn kò si fọhùn, nwọn dakẹ jẹ, nwọn kò si dahùn mọ́. |
|
| 17 |
|
| Bẹ̃li emi o si dahùn nipa ti emi, emi pẹlu yio si fi ìmọ mi hàn. |
|
| 18 |
|
| Nitoripe emi kún fun ọ̀rọ sisọ, ẹmi nrọ̀ mi ni inu mi. |
|
| 19 |
|
| Kiyesi i, ikùn mi dabi ọti-waini, ti kò ni oju-iho; o mura tan lati bẹ́ bi igo-awọ titun. |
|
| 20 |
|
| Emi o sọ, ki ara ki o le rọ̀ mi, emi o ṣi ète mi, emi o si dahùn. |
|
| 21 |
|
| Lotitọ emi kì yio ṣe ojusaju enia, bẹ̃li emi kì yio si ṣe ipọnni fun ẹnikan. |
|
| 22 |
|
| Nitoripe emi kò mọ̀ ọ̀rọ ipọnni sọ, ni ṣiṣe bẹ̃ Ẹlẹda mi yio mu mi kuro lọgan. |
|
|
|
|