|
| 1 |
|
| NJẸ nitorina, Jobu, emi bẹ̀ ọ, gbọ́ ọ̀rọ mi, ki o si fetisi ọ̀rọ mi! |
|
| 2 |
|
| Kiyesi i nisisiyi, emi ya ẹnu mi, ahọn mi si sọ̀rọ li ẹnu mi. |
|
| 3 |
|
| Ọ̀rọ mi yio si jasi iduroṣinṣin ọkàn mi, ete mi yio si sọ ìmọ mi jade dajudaju. |
|
| 4 |
|
| Ẹmi Ọlọrun li o ti da mi, ati imisi Olodumare li o ti fun mi ni ìye. |
|
| 5 |
|
| Bi iwọ ba le da mi lohùn, tò ọ̀rọ rẹ lẹsẹsẹ niwaju mi, dide duro! |
|
| 6 |
|
| Kiyesi i, bi iwọ jẹ ti Ọlọrun, bẹ̃li emi na; lati erupẹ wá ni a si ti dá mi pẹlu. |
|
| 7 |
|
| Kiyesi i, ẹ̀ru nla mi kì yio bà ọ, bẹ̃li ọwọ mi kì yio wuwo si ọ lara. |
|
| 8 |
|
| Nitõtọ iwọ sọ li eti mi, emi si gbọ́ ọ̀rọ rẹ wipe, |
|
| 9 |
|
| Emi mọ́, laini irekọja, alaiṣẹ li emi, bẹ̃li aiṣedede kò si li ọwọ mi. |
|
| 10 |
|
| Kiyesi i, ẹ̀fẹ li o fẹ si mi, o kà mi si ọ̀ta rẹ̀. |
|
| 11 |
|
| O kàn ẹsẹ mi sinu àba, o kiyesi ipa-irin mi gbogbo. |
|
| 12 |
|
| Kiyesi i, ninu eyi iwọ ṣìna! emi o da ọ lohùn pe: Ọlọrun tobi jù enia lọ! |
|
| 13 |
|
| Nitori kini iwọ ṣe mba a jà pe: on kì isọrọ̀kọrọ kan nitori iṣẹ rẹ̀? |
|
| 14 |
|
| Nitoripe Ọlọrun sọ̀rọ lẹkan, ani lẹkeji ṣugbọn enia kò roye rẹ̀. |
|
| 15 |
|
| Ninu àla, li ojuran oru, nigbati orun ìjika ba kùn enia lọ, ni isunyẹ lori bùsun. |
|
| 16 |
|
| Nigbana ni iṣi eti enia, a si fi èdidi di ẹkọ wọn. |
|
| 17 |
|
| Ki o lè ifa enia sẹhin kuro ninu ete rẹ̀, ki o si pa igberaga mọ́ kuro lọdọ enia. |
|
| 18 |
|
| O si fa ọkàn rẹ̀ pada kuro ninu iho, ati ẹmi rẹ̀ lati ṣègbe lọwọ idà. |
|
| 19 |
|
| A si fi irora nà a lori ibùsun rẹ̀, pẹlupẹlu a fi ijà egungun rẹ̀ ti o duro pẹ́, nà a. |
|
| 20 |
|
| Bẹ̃li ẹmi rẹ̀ kọ̀ onjẹ, ati ọkàn rẹ̀ kọ̀ onjẹ didùn. |
|
| 21 |
|
| Ẹran ara rẹ̀ rùn, titi a kò si fi lè ri i mọ́; egungun rẹ̀ ti a kò ri, si ta jade. |
|
| 22 |
|
| Ani ọkàn rẹ̀ sunmọ isa-okú, ati ẹmi rẹ̀ sunmọ ọdọ awọn iranṣẹ ikú. |
|
| 23 |
|
| Bi onṣẹ kan ba wà lọdọ rẹ̀, ẹniti nṣe alagbawi, ọkan ninu ẹgbẹrun lati fi ọ̀na pipé han ni: |
|
| 24 |
|
| Nigbana ni o ṣore-ọfẹ fun u, o si wipe, Gbà a kuro ninu ilọ sinu ihò, emi ti ri irapada! |
|
| 25 |
|
| Ara rẹ̀ yio si já yọ̀yọ̀ jù ti ọmọ kekere, yio si tún pada si ọjọ igba ewe rẹ̀. |
|
| 26 |
|
| O gbadura sọdọ Ọlọrun, on o si ṣe oju rere si i, o si mu enia ri oju rẹ̀ pẹlu ayọ̀, on o san ododo rẹ̀ pada fun enia. |
|
| 27 |
|
| O bojuwo enia, bi ẹnikan ba si wipe, Emi ṣẹ̀, mo si ti yi eyi ti o tọ́ po, a kò si sẹsan rẹ̀ fun mi; |
|
| 28 |
|
| O ti gba ọkàn mi kuro ninu ilọ sinu ihò, ẹmi mi yio si ri imọlẹ! |
|
| 29 |
|
| Wò o! nkan wọnyi li Ọlọrun imaṣe fun enia nigba meji, ati nigba mẹta, |
|
| 30 |
|
| Lati mu ọkàn rẹ̀ pada kuro ninu ihò, lati fi imọlẹ alãyè mọ́ si i. |
|
| 31 |
|
| Jobu! kiyesi i gidigidi, ki o si fetisilẹ si mi; pa ẹnu rẹ mọ́, emi o si ma sọ! |
|
| 32 |
|
| Bi iwọ ba si ni ohun iwi, da mi lohùn, mã sọ, nitoripe emi nfẹ da ọ lare. |
|
| 33 |
|
| Bi bẹ̃ kọ̀, gbọ temi, pa ẹnu rẹ mọ́; emi o si kọ́ ọ li ọgbọ́n. |
|
|
|
|