|
| 1 |
|
| OLUWA da Jobu lohùn si i pẹlu, o si wipe, |
|
| 2 |
|
| Ẹniti mba Olodumare jà, yio ha kọ́ ọ li ẹkọ́? ẹniti mba Ọlọrun wi, jẹ ki o dahùn! |
|
| 3 |
|
| Nigbana ni Jobu da Oluwa lohùn, o si wipe: |
|
| 4 |
|
| Kiyesi i, ẹgbin li emi; ohùn kili emi o da? emi o fi ọwọ mi le ẹnu mi. |
|
| 5 |
|
| Ẹ̃kan ni mo sọ̀rọ̀, ṣugbọn emi kì yio si tun sọ mọ, lẹ̃meji ni, emi kò si le iṣe e mọ́. |
|
| 6 |
|
| Nigbana ni OLUWA da Jobu lohùn lati inu ìji ajayika wá o si wipe: |
|
| 7 |
|
| Di àmure giri li ẹgbẹ rẹ bi ọkunrin, emi o bi ọ lere, ki iwọ ki o si kọ́ mi li ẹkọ́. |
|
| 8 |
|
| Iwọ ha fẹ imu idajọ mi di asan? iwọ o si da mi lẹbi, ki iwọ ki o le iṣe olododo? |
|
| 9 |
|
| Iwọ ni apá bi Ọlọrun, tabi iwọ le ifi ohùn san ãrá bi on? |
|
| 10 |
|
| Fi ọlanla ati ọla-itayọ ṣe ara rẹ li ọṣọ, ki o si fi ogo ati ẹwa ọṣọ bò ara rẹ li aṣọ. |
|
| 11 |
|
| Mu irunu ibinu rẹ jade, kiyesi gbogbo ìwa igberaga, ki o si rẹ̀ ẹ silẹ. |
|
| 12 |
|
| Wò gbogbo ìwa igberaga, ki o si rẹ̀ ẹ silẹ, ki o si tẹ enia buburu mọlẹ ni ipo wọn. |
|
| 13 |
|
| Fi wọn sin pọ̀ ninu erupẹ, ki o si di oju wọn ni ikọkọ. |
|
| 14 |
|
| Nigbana li emi o yìn ọ pe, ọwọ ọ̀tun ara rẹ le igba ọ la. |
|
| 15 |
|
| Njẹ nisisiyi kiyesi Behemotu ti mo da pẹlu rẹ, on a ma jẹ koriko bi ọ̀da-malu. |
|
| 16 |
|
| Wò o nisisiyi, agbara rẹ̀ wà li ẹgbẹ́ rẹ̀, ati ipa rẹ̀ ninu iṣan ikún rẹ̀. |
|
| 17 |
|
| On a ma jù ìru rẹ̀ bi igi kedari, iṣan itan rẹ̀ dijọ pọ̀. |
|
| 18 |
|
| Egungun rẹ̀ ni ogusọ idẹ, egungun rẹ̀ dabi ọpa irin. |
|
| 19 |
|
| On ni olu nipa ọ̀na Ọlọrun; ẹniti o da a o fi idà rẹ̀ le e lọwọ. |
|
| 20 |
|
| Nitõtọ oke nlanla ni imu ohun jijẹ fun u wá, nibiti gbogbo ẹranko igbẹ ima ṣire. |
|
| 21 |
|
| O dubulẹ labẹ igi Lotosi, ninu ifefe bibò ati ẹrẹ. |
|
| 22 |
|
| Igi Lotosi ṣiji wọn bò o, igi arọrọ odò yi i kakiri. |
|
| 23 |
|
| Kiyesi i, odò nla ṣan jọjọ, on kò salọ, o wà lailewu bi o ba ṣe odò Jordani ti ṣan lọ si ẹnu rẹ̀. |
|
| 24 |
|
| Ẹnikan ha le imu u li oju rẹ̀ tabi a ma fi ọkọ gun imú rẹ̀? |
|
|
|
|