|
| 1 |
|
| IWỌ le ifi ìwọ fa Lefiatani [ọni nla] jade, tabi iwọ le imu ahọn rẹ̀ ninu okùn? |
|
| 2 |
|
| Iwọ le ifi ìwọ bọ̀ ọ ni imu, tabi o le ifi ẹgun lu u li ẹrẹkẹ? |
|
| 3 |
|
| On o ha jẹ bẹ ẹ̀bẹ lọdọ rẹ li ọ̀pọlọpọ bi, on o ha ba ọ sọ̀rọ pẹlẹ? |
|
| 4 |
|
| On o ha ba ọ dá majẹmu bi, iwọ o ha ma mu u ṣe iranṣẹ lailai bi? |
|
| 5 |
|
| Iwọ ha le ba a ṣire bi ẹnipe ẹiyẹ ni, tabi iwọ o dè e fun awọn ọmọbinrin iranṣẹ rẹ? |
|
| 6 |
|
| Ẹgbẹ awọn apẹja yio ha ma tà a bi, nwọn o ha pin i lãrin awọn oniṣowo? |
|
| 7 |
|
| Iwọ le isọ awọ rẹ̀ kun fun irin abeti, tabi iwọ o sọ ori rẹ̀ kún fun ẹṣín apẹja. |
|
| 8 |
|
| Fi ọwọ rẹ le e lara, iwọ o ranti ìja na, iwọ kì yio ṣe bẹ̃ mọ. |
|
| 9 |
|
| Kiyesi i, abá nipasẹ rẹ̀ ni asan, ni kìki ìri rẹ̀ ara kì yio ha rọ̀ ọ wẹsi? |
|
| 10 |
|
| Kò si ẹni-alaiya lile ti o le iru u soke; njẹ tali o le duro niwaju rẹ̀? |
|
| 11 |
|
| Tani o ṣaju ṣe fun mi, ti emi iba fi san fun u? ohunkohun ti mbẹ labẹ ọrun gbogbo ti emi ni. |
|
| 12 |
|
| Emi kì yio fi ipin ara rẹ̀ pamọ, tabi ipá rẹ̀, tabi ihamọra rẹ̀ ti o li ẹwà. |
|
| 13 |
|
| Tani yio le iridi oju aṣọ apata rẹ̀, tabi tani o le isunmọ ọ̀na meji ehin rẹ̀. |
|
| 14 |
|
| Tani o le iṣi ilẹkun iwaju rẹ̀? ayika ehin rẹ̀ ni ìbẹru nla. |
|
| 15 |
|
| Ipẹ lile ni igberaga rẹ̀, o pade pọ mọtimọti bi ami edidi, |
|
| 16 |
|
| Ekini fi ara mọ ekeji tobẹ̃ ti afẹfẹ kò le iwọ̀ arin wọn. |
|
| 17 |
|
| Ekini fi ara mọra ekeji rẹ̀, nwọn lẹmọ pọ̀ ti a kò le iyà wọn. |
|
| 18 |
|
| Nipa sísin rẹ̀ imọlẹ a mọ́, oju rẹ̀ a si dabi ipénpeju owurọ. |
|
| 19 |
|
| Lati ẹnu rẹ̀ ni ọwọ́-iná ti ijade wá, ipẹpẹ iná a si ta jade. |
|
| 20 |
|
| Lati iho-imú rẹ̀ li ẽfin ti ijade wá, bi ẹnipe lati inu ikoko ti a fẹ́ iná ifefe labẹ rẹ̀. |
|
| 21 |
|
| Ẹmi rẹ̀ tinabọ ẹyin, ọ̀wọ-iná si ti ẹnu rẹ̀ jade. |
|
| 22 |
|
| Li ọrùn rẹ̀ li agbara kù si, ati ibinujẹ aiya si pada di ayọ̀ niwaju rẹ̀. |
|
| 23 |
|
| Jabajaba ẹran rẹ̀ dijọ pọ̀, nwọn mura giri fun ara wọn, a kò le iṣi wọn ni ipò. |
|
| 24 |
|
| Aiya rẹ̀ duro gbagigbagi bi okuta, ani o le bi iya-ọlọ. |
|
| 25 |
|
| Nigbati o ba gbe ara rẹ̀ soke, awọn alagbara a bẹ̀ru, nitori ìbẹru nla, nwọn damu. |
|
| 26 |
|
| Idà ẹniti o ṣa a kò le iràn a, ọ̀kọ, ẹṣin tabi ọfa. |
|
| 27 |
|
| O ka irin si bi koriko gbigbẹ, ati idẹ si bi igi hihù. |
|
| 28 |
|
| Ọfa kò le imu u sá, okuta kànakana lọdọ rẹ̀ dabi akeku koriko. |
|
| 29 |
|
| O ka ẹṣin si bi akeku idi koriko, o rẹrin si ìmisi ọ̀kọ. |
|
| 30 |
|
| Okuta mimú mbẹ nisalẹ abẹ rẹ̀, o si tẹ́ ohun mimú ṣonṣo sori ẹrẹ. |
|
| 31 |
|
| O mu ibu omi hó bi ìkoko, o sọ agbami okun dabi kolobó ìkunra. |
|
| 32 |
|
| O mu ipa-ọ̀na tàn lẹhin rẹ̀, enia a ma ka ibu si ewú arugbo. |
|
| 33 |
|
| Lori ilẹ aiye kò si iru rẹ̀, ti a da laini ìbẹru. |
|
| 34 |
|
| O bojuwo ohun giga gbogbo, o si nikan jasi ọba lori gbogbo awọn ọmọ igberaga. |
|
|
|
|