|
| 1 |
|
| NJẸ pè nisisiyi! bi ẹnikan ba wà ti yio da ọ lohùn, tabi tani ninu awọn ẹni-mimọ́ ti iwọ o wò? |
|
| 2 |
|
| Nitoripe ibinu pa alaimoye, irúnu a si pa òpe enia. |
|
| 3 |
|
| Emi ti ri alaimoye ti o ta gbongbò mulẹ̀, ṣugbọn lojukanna mo fi ibujoko rẹ̀ bú. |
|
| 4 |
|
| Awọn ọmọ rẹ̀ kò jina sinu ewu, a si tẹ̀ wọn mọlẹ loju ibode, bẹ̃ni kò si alãbò kan. |
|
| 5 |
|
| Ikore oko ẹniti awọn ẹniti ebi npa jẹrun, ti nwọn si wọnú ẹ̀gun lọ ikó, awọn igara si gbe ohùn ini wọn mì. |
|
| 6 |
|
| Bi ipọnju kò tilẹ̀ tinu erupẹ jade wá nì, ti iyọnu kò si tinu ilẹ hù jade wá. |
|
| 7 |
|
| Ṣugbọn a bi enia sinu wàhala, gẹgẹ bi ìpẹpẹ iná ti ima ta sokè. |
|
| 8 |
|
| Sọdọ Ọlọrun li emi lè ma ṣe awári, li ọwọ Ọlọrun li emi lè ma fi ọ̀ran mi le. |
|
| 9 |
|
| Ẹniti o ṣe ohun ti o tobi, ti a kò lè iṣe awári, ohun iyanu laini iye. |
|
| 10 |
|
| Ti nrọ̀jo si ilẹ aiye, ti o si nrán omi sinu ilẹ̀kilẹ. |
|
| 11 |
|
| Lati gbe awọn onirẹlẹ leke, ki a le igbé awọn ẹni ibinujẹ ga si ibi ailewu. |
|
| 12 |
|
| O yi ìmọ awọn alarekerekè po, bẹ̃li ọwọ wọn kò lè imu idawọle wọn ṣẹ. |
|
| 13 |
|
| O mu awọn ọlọgbọ́n ninu arekereke ara wọn, ati ìmọ awọn onroro li o tãri ṣubu li ògedengbè. |
|
| 14 |
|
| Nwọn sure wọ inu òkunkun li ọ̀san, nwọn si nfọwọ talẹ̀ li ọ̀sangangan bi ẹnipe li oru. |
|
| 15 |
|
| Ṣugbọn o gba talakà là kuro li ọwọ idà, lọwọ ẹnu wọn, ati lọwọ awọn alagbara. |
|
| 16 |
|
| Bẹ̃ni abá wà fun talaka, aiṣotitọ si pa ẹnu rẹ̀ mọ. |
|
| 17 |
|
| Kiyesi i, ibukún ni fun ẹniti Ọlọrun bawi, nitorina má ṣe gan ìbawi Olodumare. |
|
| 18 |
|
| Nitoripe on a mu ni lara kan, a si di idi itura, o ṣa lọgbẹ, ọwọ rẹ̀ a si mu jina. |
|
| 19 |
|
| Yio gbà ọ ninu ipọnju mẹfa, ani ninu meje ibi kan kì yio ba ọ. |
|
| 20 |
|
| Ninu ìyan yio gbà ọ lọwọ ikú, ati ninu ogun yio gbà ọ lọwọ idà. |
|
| 21 |
|
| A o pa ọ mọ kuro lọwọ ìna ahọn, bẹ̃ni iwọ kì yio bẹ̀ru iparun nigbati o ba dé. |
|
| 22 |
|
| Ẹrin iparun ati ti iyàn ni iwọ o rín, bẹ̃ni iwọ kì yio bẹ̀ru ẹranko ilẹ aiye. |
|
| 23 |
|
| Nitoripe iwọ o ba okuta ìgbẹ mulẹ̀, awọn ẹranko ìgbẹ yio wà pẹlu rẹ li alafia. |
|
| 24 |
|
| Iwọ o si mọ̀ pe alafia ni ibujoko rẹ wà, iwọ o si ma ṣe ibẹ̀wo ibujoko rẹ, iwọ kì yio ṣìna. |
|
| 25 |
|
| Iwọ o si mọ̀ pẹlu pe iru-ọmọ rẹ yio si pọ̀, ati awọn ọmọ-ọmọ rẹ yio ri bi koriko ìgbẹ. |
|
| 26 |
|
| Iwọ o wọ isa-okú rẹ lọ li ògbologbo ọjọ bi apo-ọka ti o gbó, ti a si nko ni igbà ikore rẹ̀. |
|
| 27 |
|
| Kiyesi i, awa ti nwadi rẹ̀, bẹ̃li o ri! gbà a gbọ́, ki o si mọ̀ pe fun ire ara rẹ ni! |
|
|
|
|