|
| 1 |
|
| JOBU si dahùn o si wipe, |
|
| 2 |
|
| A! a ba le iwọ̀n ibinujẹ mi ninu òṣuwọn, ki a si le igbe ọ̀fọ mi le ori òṣuwọn ṣọkan pọ̀! |
|
| 3 |
|
| Njẹ nisisiyi, iba wuwo jù iyanrin okun lọ: nitorina li ọ̀rọ mi ṣe ntàse. |
|
| 4 |
|
| Nitoripe ọfa Olodumare wọ̀ mi ninu, oró eyiti ọkàn mi mu; ipaiya-ẹ̀ru Ọlorun dotì mi. |
|
| 5 |
|
| Kẹtẹkẹtẹ ìgbẹ a ma dún, nigbati o ba ni koriko, tabi ọdá-malu a ma dún sori ijẹ rẹ̀? |
|
| 6 |
|
| A le jẹ ohun ti kò li adùn li aini iyọ̀, tabi adùn wà ninu funfun ẹyin? |
|
| 7 |
|
| Ohun ti ọkàn mi kọ̀ lati tọ́, on li o dàbi onjẹ mi ti kò ni adùn. |
|
| 8 |
|
| A! emi iba lè ri iberè mi gbà; ati pe, ki Ọlọrun le fi ohun ti emi ṣafẹri fun mi. |
|
| 9 |
|
| Ani, Ọlọrun iba jẹ pa mi run, ti on iba jẹ ṣiwọ rẹ̀ ki o si ké mi kuro. |
|
| 10 |
|
| Nigbana ni emi iba ni itunú sibẹ, ani emi iba mu ọkàn mi le ninu ibinujẹ mi ti kò da ni si: nitori emi kò fi ọ̀rọ Ẹni Mimọ́ nì sin ri. |
|
| 11 |
|
| Kili agbara mi ti emi o fi dabá? ki si li opin mi ti emi o fi fà ẹmi mi gùn? |
|
| 12 |
|
| Agbara mi iṣe agbara okuta bi, tabi ẹran ara mi iṣe idẹ? |
|
| 13 |
|
| Iranlọwọ mi kò ha wà ninu mi: ọgbọn ha ti salọ kuro lọdọ mi bi? |
|
| 14 |
|
| Ẹniti aya rẹ̀ yọ́ danu tan ni a ba ma ṣãnu fun lati ọdọ ọrẹ rẹ̀ wá, ki o má kọ̀ ibẹru Olodumare silẹ̀. |
|
| 15 |
|
| Awọn ará mi ṣẹ̀tan bi odò ṣolõ, bi iṣàn gburu omi odò ṣolõ, nwọn ṣàn kọja lọ. |
|
| 16 |
|
| Ti o dúdu nitori omi didì, ati nibiti òjo didì gbe lùmọ si. |
|
| 17 |
|
| Nigbakũgba ti nwọn ba gboná, nwọn a si yọ́ ṣanlọ, nigbati õrùn ba mú, nwọn si gbẹ kurò ni ipò wọn. |
|
| 18 |
|
| Iya ọ̀na wọn a si yipada sapakan, nwọn goke si ibi asan, nwọn si run. |
|
| 19 |
|
| Ẹgbẹ ogun Tema nwoye, awọn ọwọ́-èro Seba duro de wọn. |
|
| 20 |
|
| Nwọn dãmu, nitoriti nwọn ni abá; nwọn debẹ̀, nwọn si dãmu. |
|
| 21 |
|
| Njẹ nisisiyi, ẹnyin dabi wọn; ẹnyin ri irẹ̀silẹ mi, aiya si fò nyin. |
|
| 22 |
|
| Emi ha wipe, ẹ mu ohun fun mi wá, tabi pe, ẹ bun mi ni ẹ̀bun ninu ohun ini nyin? |
|
| 23 |
|
| Tabi, ẹ gbà mi li ọwọ ọ̀ta nì, tabi, ẹ rà mi padà kuro lọwọ alagbara nì! |
|
| 24 |
|
| Ẹ kọ́ mi, emi o si pa ẹnu mi mọ́; ki ẹ si mu mi moye ibiti mo gbe ti ṣìna. |
|
| 25 |
|
| Wo! bi ọ̀rọ otitọ ti li agbara to! ṣugbọn kini aròye ibawi nyin jasi? |
|
| 26 |
|
| Ẹnyin ṣebi ẹ o ba ọ̀rọ ati ohùn ẹnu ẹniti o taku wi, ti o dabi afẹfẹ. |
|
| 27 |
|
| Ani ẹnyin ṣẹ́ gege fun alainibaba, ẹnyin si da iye le ọrẹ nyin. |
|
| 28 |
|
| Nitorina ki eyi ki o tó fun nyin: ẹ ma wò mi! nitoripe o hàn gbangba pe: li oju nyin ni emi kì yio ṣeke. |
|
| 29 |
|
| Emi bẹ̀ nyin, ẹ pada, ki o má ṣe jasi ẹ̀ṣẹ: ani ẹ si tun pada, are mi mbẹ ninu ọ̀ran yi. |
|
| 30 |
|
| Aiṣedede ha wà li ahọn mi? njẹ itọwò ẹnu mi kò kuku le imọ̀ ohun ti o burujù? |
|
|
|
|