Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| KÌ iṣe fun wa, Oluwa, kì iṣe fun wa, bikoṣe orukọ rẹ li a fi ogo fun nitori ãnu rẹ, ati nitori otitọ rẹ. |
| 2 |
| Nitori kili awọn keferi yio ṣe wipe, Nibo li Ọlọrun wọn wà nisisiyi? |
| 3 |
| Ṣugbọn Ọlọrun wa mbẹ li ọrun: o nṣe ohun-kohun ti o wù u. |
| 4 |
| Fadaka ati wura li ere wọn, iṣẹ ọwọ enia. |
| 5 |
| Nwọn li ẹnu, ṣugbọn nwọn kò sọ̀rọ: nwọn li oju, ṣugbọn nwọn kò riran. |
| 6 |
| Nwọn li eti, ṣugbọn nwọn kò gbọran: nwọn ni imu, ṣugbọn nwọn kò gbõrun. |
| 7 |
| Nwọn li ọwọ, ṣugbọn nwọn kò lò o: nwọn li ẹsẹ, ṣugbọn nwọn kò rìn: bẹ̃ni nwọn kò sọ̀rọ lati ọfun wọn jade. |
| 8 |
| Awọn ti nṣe wọn dabi wọn; bẹ̃li olukuluku ẹniti o gbẹkẹle wọn. |
| 9 |
| Israeli, iwọ gbẹkẹle Oluwa: on ni iranlọwọ wọn ati asà wọn. |
| 10 |
| Ara-ile Aaroni, gbẹkẹle Oluwa, on ni iranlọwọ wọn ati asà wọn. |
| 11 |
| Ẹnyin ti o bẹ̀ru Oluwa, gbẹkẹle Oluwa: on ni iranlọwọ wọn ati asà wọn. |
| 12 |
| Oluwa ti nṣe iranti wa: yio bùsi i fun wa: yio bùsi i fun ara-ile Israeli; yio bùsi i fun ara-ile Aaroni. |
| 13 |
| Yio bùsi i fun awọn ti o bẹ̀ru Oluwa, ati ewe ati àgba. |
| 14 |
| Oluwa yio mu nyin bisi i siwaju ati siwaju, ẹnyin ati awọn ọmọ nyin. |
| 15 |
| Ẹnyin li ẹni-ibukún Oluwa, ti o da ọrun on aiye. |
| 16 |
| Ọrun ani ọrun ni ti Oluwa; ṣugbọn aiye li o fi fun awọn ọmọ enia. |
| 17 |
| Okú kò yìn Oluwa, ati gbogbo awọn ti o sọkalẹ lọ sinu idakẹ. |
| 18 |
| Ṣugbọn awa o ma fi ibukún fun Oluwa, lati igba yi lọ ati si i lailai. Ẹ yìn Oluwa. |
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/psalms/115.mp3
150
115