|
| 1 |
|
| Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa: nitoriti o ṣeun; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. |
|
| 2 |
|
| Ẹ fi ọpẹ fun Ọlọrun awọn ọlọrun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. |
|
| 3 |
|
| Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa awọn oluwa: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. |
|
| 4 |
|
| Fun on nikan ti nṣe iṣẹ iyanu nla: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. |
|
| 5 |
|
| Fun ẹniti o fi ọgbọ́n da ọrun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. |
|
| 6 |
|
| Fun ẹniti o tẹ́ ilẹ lori omi: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. |
|
| 7 |
|
| Fun ẹniti o dá awọn imọlẹ nla: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. |
|
| 8 |
|
| Õrùn lati jọba ọsan: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai: |
|
| 9 |
|
| Oṣupa ati irawọ lati jọba oru: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. |
|
| 10 |
|
| Fun ẹniti o kọlù Egipti lara awọn akọbi wọn: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. |
|
| 11 |
|
| O si mu Israeli jade kuro lãrin wọn: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai: |
|
| 12 |
|
| Pẹlu ọwọ agbara, ati apa ninà: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. |
|
| 13 |
|
| Fun ẹniti o pin Okun pupa ni ìya: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai: |
|
| 14 |
|
| O si mu Israeli kọja lọ larin rẹ̀: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. |
|
| 15 |
|
| Ṣugbọn o bi Farao ati ogun rẹ̀ ṣubu ninu Okun pupa: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. |
|
| 16 |
|
| Fun ẹniti o sin awọn enia rẹ̀ la aginju ja: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. |
|
| 17 |
|
| Fun ẹniti o kọlù awọn ọba nla: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. |
|
| 18 |
|
| O si pa awọn ọba olokiki: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. |
|
| 19 |
|
| Sihoni, ọba awọn ara Amori: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. |
|
| 20 |
|
| Ati Ogu, ọba Baṣani: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. |
|
| 21 |
|
| O si fi ilẹ wọn funni ni ini, nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. |
|
| 22 |
|
| Ini fun Israeli, iranṣẹ rẹ̀; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. |
|
| 23 |
|
| Ẹniti o ranti wa ni ìwa irẹlẹ wa; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. |
|
| 24 |
|
| O si dá wa ni ìde lọwọ awọn ọta wa; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. |
|
| 25 |
|
| Ẹniti o nfi onjẹ fun ẹda gbogbo: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai; |
|
| 26 |
|
| Ẹ fi ọpẹ fun Ọlọrun ọrun; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. |
|
|
|
|