×

Bibeli Mimọ Bible 2012

Saamu 137

1
LI ẹba odò Babeli, nibẹ li awa gbe joko, awa si sọkun nigbati awa ranti Sioni.
2
Awa fi duru wa kọ́ si ori igi wíllo ti o wà lãrin rẹ̀.
3
Nitoripe nibẹ li awọn ti o kó wa ni igbekun bère orin lọwọ wa; ati awọn ti o ni wa lara bère idaraya wipe; Ẹ kọ orin Sioni kan fun wa.
4
Awa o ti ṣe kọ orin Oluwa ni ilẹ àjeji?
5
Jerusalemu, bi emi ba gbagbe rẹ, jẹ ki ọwọ ọtún mi ki o gbagbe ìlò rẹ̀.
6
Bi emi kò ba ranti rẹ, jẹ ki ahọn mi ki o lẹ̀ mọ èrìgì mi; bi emi kò ba fi Jerusalemu ṣaju olori ayọ̀ mi gbogbo.
7
Oluwa, ranti ọjọ Jerusalemu lara awọn ọmọ Edomu, awọn ẹniti nwipe, Wó o palẹ, wó o palẹ, de ipilẹ rẹ̀!
8
Iwọ, ọmọbinrin Babeli, ẹniti a o parun; ibukún ni fun ẹniti o san a fun ọ bi iwọ ti hù si wa.
9
Ibukún li ẹniti o mu, ti o si fi ọmọ wẹwẹ rẹ ṣán okuta.
Yoruba Bible 2012
Yoruba Bible Crowther Version The Bible Society of Nigeria, 2012
:
Fipamọ Awọn akọsilẹ