Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMY) 2014
|
| 1 |
| OLÚWA gbọ̀ àdúrà mi, fetísí igbe mi fún àánú; nínú òtítọ́ àti òdodo Rẹ wá fún ìrànlọ́wọ́ mi |
| 2 |
| Má ṣe mú ìránṣẹ́ Rẹ wá sí ìdájọ́, nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láàyè tí ó ṣe òdodo níwájú Rẹ. |
| 3 |
| Ọ̀ta ń lé pa mi, ó fún mi pa mọ́ ilẹ̀; ó mú mi gbé nínú òkùnkùn bí àwọn tí ó ti kú ti pẹ́. |
| 4 |
| Nítorí náà ẹ̀mí mi ṣàárẹ̀ nínú mi; ọkàn mi tí ó wà nínú mi dààmú. |
| 5 |
| Èmi rántí ọjọ́ tí ó ti pẹ́; èmi ń ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ Rẹ mo sì ṣe àkíyèsí ohun tí ọwọ́ Rẹ ti ṣe. |
| 6 |
| Èmi na ọwọ́ mi jáde sí ọ: òrùgbẹ Rẹ gbẹ ọkàn mi bí i ìyàngbẹ ilẹ̀. Sela |
| 7 |
| Dámilóhùn kánkán, OLÚWA; ó Rẹ̀ ẹ̀mí mi Má ṣe pa ojú Rẹ mọ́ kúrò lára mi tàbí èmi yóò dàbí àwọn tí ó lọ sínú ihò |
| 8 |
| Jẹ́ kí òwúrọ̀ mú ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tí kì í kùnà wá fún mi, nítorí èmi ti gbẹ́kẹ̀ mi lé ọ. Fí ọ̀nà tí èmi i bá rìn hàn mí, nítorí sí ọ ni èmi gbé ọkàn mi sókè. |
| 9 |
| Gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, OLÚWA, nítorí èmi fí ara mi pamọ́ sínú Rẹ̀. |
| 10 |
| Kọ́ mi láti ṣe ìfẹ́ Rẹ, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run mi jẹ́ kí ẹ̀mí Rẹ dídára darí mi sí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú. |
| 11 |
| Nítorí orúkọ Rẹ, OLÚWA, sọ ayé mi di ààyè; nínú òdodo Rẹ mú mi jáde nínú wàhálà. |
| 12 |
| Nínú ìfẹ́ Rẹ tí kì í kùnà, ké àwọn ọ̀ta mi kúrò, run gbogbo àwọn ọ̀tá mi, nítorí èmi ni ìránṣẹ́ Rẹ. |
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba2014/psalms/143.mp3
150
143