×

Yoruba Bible 2010

Saamu 2

1
Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń bínú fùfù tí àwọn eniyan ń gbìmọ̀ asán?
2
Àwọn ọba ayé kó ara wọn jọ, àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n dojú kọ OLUWA ati àyànfẹ́ rẹ̀.
3
Wọn ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á fa ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi dè wá já kí á sì yọ ara wa kúrò lóko ẹrú wọn.”
4
Ẹni tí ó gúnwà lọ́run ń fi wọ́n rẹ́rìn-ín; OLUWA sì ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́.
5
Lẹ́yìn náà, yóo sọ̀rọ̀ sí wọn ninu ibinu rẹ̀, yóo dẹ́rùbà wọ́n gidigidi ninu ìrúnú rẹ̀,
6
Yóo wí pé, “Mo ti fi ọba mi jẹ, ní Sioni, lórí òkè mímọ́ mi.”
7
N óo kéde ohun tí OLUWA pa láṣẹ ní ti èmi ọba; Ó wí fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi, lónìí ni mo bí ọ.
8
Bèèrè lọ́wọ́ mi, èmi ó sì fún ọ ní àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo ayé yóo sì di tìrẹ.
9
Ìwọ óo fi ọ̀pá irin fọ́ wọn, o óo sì fọ́ wọn túútúú bí ìkòkò amọ̀.”
10
Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ kọ́gbọ́n; ẹ̀yin onídàájọ́ ayé, ẹ gba ìkìlọ̀.
11
Ẹ fi ìbẹ̀rù sin OLUWA, ẹ yọ̀ pẹlu ìwárìrì.
12
Ẹ júbà ọmọ náà, kí ó má baà bínú, kí ó má baà pa yín run lójijì; nítorí a máa yára bínú. Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo àwọn tí ó wá ààbò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.
Yoruba Bible 2010
Bible Society of Nigeria 1900/2010
:
Fipamọ Awọn akọsilẹ