Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| ṢE idajọ mi, Oluwa; nitori ti mo ti nrìn ninu ìwa titọ mi; emi ti gbẹkẹle Oluwa pẹlu; njẹ ẹsẹ mi kì yio yẹ̀. |
| 2 |
| Wadi mi, Oluwa, ki o si ridi mi; dán inu mi ati ọkàn mi wò. |
| 3 |
| Nitoriti iṣeun-ifẹ rẹ mbẹ niwaju mi: emi si ti nrìn ninu otitọ rẹ. |
| 4 |
| Emi kò ba ẹni asan joko, bẹ̃li emi kì yio ba awọn alayidayida wọle. |
| 5 |
| Emi ti korira ijọ awọn oluṣe-buburu; emi kì yio si ba awọn enia buburu joko. |
| 6 |
| Emi o wẹ̀ ọwọ mi li ailẹṣẹ: bẹ̃li emi o si yi pẹpẹ rẹ ká, Oluwa. |
| 7 |
| Ki emi ki o le fi ohùn ọpẹ rò kalẹ, ti emi o si ma sọ̀rọ gbogbo iṣẹ iyanu rẹ. |
| 8 |
| Oluwa, emi ti nfẹ ibujoko ile rẹ, ibi agọ ọlá rẹ. |
| 9 |
| Máṣe kó ọkàn mi pọ̀ pẹlu awọn ẹlẹṣẹ, tabi ẹmi mi pẹlu awọn enia-ẹ̀jẹ. |
| 10 |
| Li ọwọ ẹniti ìwa-ìka mbẹ, ọwọ ọtún wọn si kún fun abẹtẹlẹ. |
| 11 |
| Ṣugbọn bi o ṣe ti emi, emi o ma rìn ninu ìwatitọ mi: rà mi pada, ki o si ṣãnu fun mi. |
| 12 |
| Ẹsẹ mi duro ni ibi titẹju: ninu awọn ijọ li emi o ma fi ibukún fun Oluwa. |
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/psalms/026.mp3
150
26