|
| 1 |
|
| OLUWA, máṣe ba mi wi ninu ibinu rẹ: bẹ̃ni ki o máṣe nà mi ni gbigbona ibinujẹ rẹ. |
|
| 2 |
|
| Nitori ti ọfà rẹ kàn mọ́ mi ṣinṣin, ọwọ rẹ si kì mi wọ̀ mọlẹ. |
|
| 3 |
|
| Kò si ibi yíyè li ara mi nitori ibinu rẹ; bẹ̃ni kò si alafia li egungun mi nitori ẹ̀ṣẹ mi. |
|
| 4 |
|
| Nitori ti ẹbi ẹ̀ṣẹ mi bori mi mọlẹ, bi ẹrù wuwo, o wuwo jù fun mi. |
|
| 5 |
|
| Ọgbẹ mi nrùn, o si dibajẹ nitori were mi. |
|
| 6 |
|
| Emi njowere; ori mi tẹ̀ ba gidigidi; emi nṣọ̀fọ kiri li gbogbo ọjọ. |
|
| 7 |
|
| Nitoriti iha mi kún fun àrun ẹgbin; kò si si ibi yiyè li ara mi. |
|
| 8 |
|
| Ara mi hù, o si kan bajẹ; emi ti nkerora nitori aisimi aiya mi. |
|
| 9 |
|
| Oluwa, gbogbo ifẹ mi mbẹ niwaju rẹ; ikerora mi kò si pamọ́ kuro lọdọ rẹ. |
|
| 10 |
|
| Aiya mi nmi-hẹlẹ, agbara mi yẹ̀ mi silẹ: bi o ṣe ti imọlẹ oju mi ni, kò si lara mi. |
|
| 11 |
|
| Awọn olufẹ ati awọn ọrẹ mi duro li òkere kuro ni ìna mi, ati awọn ibatan mi duro li òkere rére. |
|
| 12 |
|
| Awọn pẹlu ti nwá ọkàn mi dẹkùn silẹ fun mi; ati awọn ti nwá ifarapa mi nsọ̀rọ ohun buburu, nwọn si ngbiro ẹ̀tan li gbogbo ọjọ. |
|
| 13 |
|
| Ṣugbọn emi, bi aditi, emi kò gbọ́; ati bi odi ti kò ya ẹnu rẹ̀. |
|
| 14 |
|
| Bẹ̃ni mo dabi ọkunrin ti kò gbọ́ran, ati li ẹnu ẹniti iyàn kò si. |
|
| 15 |
|
| Nitori, Oluwa, iwọ li emi duro dè, iwọ o gbọ́, Oluwa Ọlọrun mi. |
|
| 16 |
|
| Nitori ti mo wipe, Gbohùn mi, ki nwọn ki o má ba yọ̀ mi; nigbati ẹsẹ mi ba yọ́, nwọn o ma gbé ara wọn ga si mi. |
|
| 17 |
|
| Emi ti mura ati ṣubu, ikãnu mi si mbẹ nigbagbogbo niwaju mi. |
|
| 18 |
|
| Nitori ti emi o jẹwọ ẹ̀ṣẹ mi; emi o kãnu nitori ẹ̀ṣẹ mi. |
|
| 19 |
|
| Ṣugbọn ara yá awọn ọta mi, ara wọn le; awọn ti o korira mi lodi npọ̀ si i. |
|
| 20 |
|
| Awọn ti o si nfi buburu san rere li ọta mi; nitori emi ntọpa ohun ti iṣe rere. |
|
| 21 |
|
| Oluwa, máṣe kọ̀ mi silẹ; Ọlọrun mi, máṣe jina si mi. |
|
| 22 |
|
| Yara lati ran mi lọwọ, Oluwa igbala mi. |
|
|
|
|