Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| GBOHÙN mi nigbati mo ba npè, Ọlọrun ododo mi: iwọ li o da mi ni ìde ninu ipọnju; ṣe ojurere fun mi, ki o si gbọ́ adura mi. |
| 2 |
| Ẹnyin ọmọ enia, ẹ o ti sọ ogo mi di itiju pẹ to? ẹnyin o ti fẹ asan pẹ to, ti ẹ o si ma wá eke iṣe? |
| 3 |
| Ṣugbọn ki ẹ mọ̀ pe Oluwa yà ẹni ayanfẹ sọ̀tọ fun ara rẹ̀: Oluwa yio gbọ́ nigbati mo ba kepè e. |
| 4 |
| Ẹ duro ninu ẹ̀ru, ẹ má si ṣe ṣẹ̀; ẹ ba ọkàn nyin sọ̀rọ lori ẹní nyin, ki ẹ si duro jẹ. |
| 5 |
| Ẹ ru ẹbọ ododo, ki ẹ si gbẹkẹ nyin le Oluwa. |
| 6 |
| Ẹni pupọ li o nwipe, Tani yio ṣe rere fun wa? Oluwa, iwọ gbé imọlẹ oju rẹ soke si wa lara. |
| 7 |
| Iwọ ti fi ayọ̀ si mi ni inu, jù igba na lọ ti ọkà wọn ati ọti-waini wọn di pupọ̀. |
| 8 |
| Emi o dubulẹ pẹlu li alafia, emi o si sùn; nitori iwọ, Oluwa, nikanṣoṣo li o nmu mi joko li ailewu. |
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/psalms/004.mp3
150
4