Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| ṢE idajọ mi, Ọlọrun, ki o si gbà ọ̀ran mi rò si alailãnu orilẹ-ède: gbà mi lọwọ ẹlẹtan ati ọkunrin alaiṣõtọ nì. |
| 2 |
| Nitori iwọ li Ọlọrun agbara mi: ẽṣe ti iwọ fi ṣa mi tì? ẽṣe ti emi fi nrìn ni igbawẹ nitori inilara ọta nì. |
| 3 |
| Rán imọlẹ rẹ ati otitọ rẹ jade, ki nwọn ki o ma ṣe amọna mi: ki nwọn ki o mu mi gùn òke mimọ́ rẹ, ati sinu agọ rẹ wọnni. |
| 4 |
| Nigbana li emi o lọ si ibi pẹpẹ Ọlọrun, sọdọ Ọlọrun ayọ̀ nla mi: nitõtọ, lara duru li emi o ma yìn ọ, Ọlọrun, Ọlọrun mi. |
| 5 |
| Ẽṣe ti ori rẹ fi tẹ̀ba, iwọ ọkàn mi? ẽṣe ti ara rẹ kò fi lelẹ ninu mi? iwọ ṣe ireti niti Ọlọrun: nitoriti emi o sa ma yìn i sibẹ, ẹniti iṣe iranlọwọ oju mi, ati Ọlọrun mi. |
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/psalms/043.mp3
150
43