Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| AIYA mi nhumọ̀ ọ̀ran rere: emi nsọ ohun ti mo ti ṣe, fun ọba ni: kalamu ayawọ akọwe li ahọn mi. |
| 2 |
| Iwọ yanju jù awọn ọmọ enia lọ: a dà ore-ọfẹ si ọ li ète: nitorina li Ọlọrun nbukún fun ọ lailai. |
| 3 |
| San idà rẹ mọ idi rẹ, Alagbara julọ, ani ogo rẹ ati ọlá-nla rẹ. |
| 4 |
| Ati ninu ọlánlá rẹ ma gẹṣin lọ li alafia, nitori otitọ ati ìwa-tutu ati ododo; ọwọ ọtún rẹ yio si kọ́ ọ li ohun ẹ̀ru. |
| 5 |
| Ọfa rẹ mu li aiya awọn ọta ọba; awọn enia nṣubu nisalẹ ẹsẹ rẹ. |
| 6 |
| Ọlọrun, lai ati lailai ni itẹ́ rẹ: ọpá-alade ijọba rẹ, ọpá-alade otitọ ni. |
| 7 |
| Iwọ fẹ ododo, iwọ korira ìwa-buburu: nitori na li Ọlọrun, Ọlọrun rẹ, ṣe fi àmi ororo ayọ̀ yà ọ ṣolori awọn ọ̀gba rẹ. |
| 8 |
| Gbogbo aṣọ rẹ li o nrun turari, ati aloe, ati kassia, lati inu ãfin ehin-erin jade ni nwọn gbe nmu ọ yọ̀. |
| 9 |
| Awọn ọmọbinrin awọn alade wà ninu awọn ayanfẹ rẹ: li ọwọ ọtún rẹ li ayaba na gbe duro ninu wura Ofiri. |
| 10 |
| Dẹti silẹ, ọmọbinrin, si ronu, si dẹ eti rẹ silẹ! gbagbe awọn enia rẹ, ati ile baba rẹ! |
| 11 |
| Bẹ̃li Ọba yio fẹ ẹwà rẹ gidigidi: nitori on li Oluwa rẹ; ki iwọ ki o si ma sìn i. |
| 12 |
| Ọmọbinrin Tire ti on ti ọrẹ; ati awọn ọlọrọ̀ ninu awọn enia yio ma bẹ̀bẹ oju-rere rẹ. |
| 13 |
| Ti ogo ti ogo li ọmọbinrin ọba na ninu ile: iṣẹ wura ọnà abẹrẹ li aṣọ rẹ̀. |
| 14 |
| Ninu aṣọ iṣẹ ọnà abẹrẹ li a o mu u tọ̀ ọba wá: awọn wundia, ẹgbẹ rẹ̀ ti ntọ̀ ọ lẹhin li a o mu tọ̀ ọ wá. |
| 15 |
| Pẹlu inu didùn ati pẹlu ayọ̀ li a o fi mu wọn wá: nwọn o si wọ̀ ãfin ọba lọ. |
| 16 |
| Nipò awọn baba rẹ li awọn ọmọ rẹ yio wà, ẹniti iwọ o ma fi jẹ oye lori ilẹ gbogbo. |
| 17 |
| Emi o ma ṣe orukọ rẹ ni iranti ni iran gbogbo: nitorina li awọn enia yio ṣe ma yìn ọ lai ati lailai. |
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/psalms/045.mp3
150
45