Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| ẸNYIN enia, gbogbo ẹ ṣapẹ; ẹ fi ohùn ayọ̀ hó ihó iṣẹgun si Ọlọrun. |
| 2 |
| Nitori Oluwa Ọga-ogo li ẹ̀ru; on li ọba nla lori ilẹ-aiye gbogbo. |
| 3 |
| On ni yio ṣẹ́ awọn enia labẹ wa, ati awọn orilẹ-ède li atẹlẹsẹ wa. |
| 4 |
| On ni yio yàn ilẹ-ini wa fun wa, ọlá Jakobu, ẹniti o fẹ. |
| 5 |
| Ọlọrun gòke lọ ti on ti ariwo, Oluwa, ti on ti iró ipè. |
| 6 |
| Ẹ kọrin iyìn si Ọlọrun, ẹ kọrin iyìn: ẹ kọrin iyìn si Ọba wa, ẹ kọrin iyìn. |
| 7 |
| Nitori Ọlọrun li Ọba gbogbo aiye: ẹ fi oye kọrin iyìn. |
| 8 |
| Ọlọrun jọba awọn keferi: Ọlọrun joko lori itẹ ìwa-mimọ́ rẹ̀. |
| 9 |
| Awọn alade awọn enia kó ara wọn jọ, ani awọn enia Ọlọrun Abrahamu: nitori asà aiye ti Ọlọrun ni: on li a gbe leke jọjọ. |
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/psalms/047.mp3
150
47