Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| ỌLỌRUN, ṣãnu fun mi: nitoriti enia nfẹ gbe mi mì; o mba mi jà lojojumọ, o nni mi lara. |
| 2 |
| Awọn ọta mi nfẹ igbe mi mì lojojumọ: nitori awọn ti nfi igberaga ba mi ja pọ̀. |
| 3 |
| Nigbati ẹ̀ru ba mbà mi, emi o gbẹkẹle ọ. |
| 4 |
| Nipa Ọlọrun li emi o ma yìn ọ̀rọ rẹ̀, Ọlọrun li emi o gbẹkẹ mi le, emi kì yio bèru: kili ẹran-ara le ṣe si mi. |
| 5 |
| Lojojumọ ni nwọn nlọ́ ọ̀rọ mi: ibi ni gbogbo ìro inu wọn si mi: |
| 6 |
| Nwọn kó ara wọn jọ, nwọn ba, nwọn kiyesi ìrin mi, nwọn ti nṣọ̀na ọkàn mi. |
| 7 |
| Nwọn ha le ti ipa aiṣedede là? ni ibinu, bi awọn enia na lulẹ̀, Ọlọrun. |
| 8 |
| Iwọ nka ìrìnkiri mi: fi omije mi sinu igo rẹ: nwọn ko ha si ninu iwe rẹ bi? |
| 9 |
| Li ọjọ ti mo ba kigbe, nigbana li awọn ọta mi yio pẹhinda: eyi li emi mọ̀: nitoripe Ọlọrun wà fun mi. |
| 10 |
| Nipa Ọlọrun li emi o ma yìn ọ̀rọ rẹ̀: nipa Oluwa li emi o ma yìn ọ̀rọ rẹ̀. |
| 11 |
| Ọlọrun li emi gbẹkẹ mi le, emi kì yio bẹ̀ru kili enia le ṣe si mi. |
| 12 |
| Ẹjẹ́ rẹ mbẹ lara mi, Ọlọrun: emi o fi iyìn fun ọ. |
| 13 |
| Nitoripe iwọ li o ti gbà ọkàn mi lọwọ ikú: iwọ ki yio ha gbà ẹsẹ mi lọwọ iṣubu? ki emi ki o le ma rìn niwaju Ọlọrun ni imọlẹ awọn alãye? |
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/psalms/056.mp3
150
56