Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| ẸNYIN ha nsọ ododo nitõtọ, ẹnyin ijọ enia? ẹnyin ha nṣe idajọ ti o ṣe titọ, ẹnyin ọmọ enia? |
| 2 |
| Nitõtọ, ẹnyin nṣiṣẹ buburu li aiya; ẹnyin nwọ̀n ìwa-agbara ọwọ nyin li aiye. |
| 3 |
| Lati inu iya wọn wá li awọn enia buburu ti ṣe iyapa: nwọn ti ṣina lojukanna ti a ti bi wọn, nwọn a ma ṣeke. |
| 4 |
| Oró wọn dabi oró ejò: nwọn dabi aditi ejò pamọlẹ ti o di ara rẹ̀ li eti; |
| 5 |
| Ti kò fẹ igbọ́ ohùn awọn atuniloju, bi o ti wù ki o ma fi ọgbọ́n ṣe ituju to. |
| 6 |
| Ká wọn li ehin, Ọlọrun, li ẹnu wọn: ká ọ̀gan awọn ọmọ kiniun nì, Oluwa. |
| 7 |
| Ki nwọn ki o yọ́ danu bi omi ti nṣàn nigbagbogbo: nigbati o ba fa ọrun lati tafà rẹ̀, ki nwọn ki o dabi ẹnipe a ke wọn ni ijanja. |
| 8 |
| Bi igbín ti a tẹ̀ rẹ́ ti o si ṣegbe: bi iṣẹnu obinrin, bẹ̃ni ki nwọn ki o má ṣe ri õrùn. |
| 9 |
| Ki ikoko nyin ki o to mọ̀ igbona ẹgún, iba tutu iba ma jo, yio fi iji gbá wọn lọ. |
| 10 |
| Olododo yio yọ̀ nigbati o ba ri ẹsan na: yio si wẹ̀ ẹsẹ rẹ̀ ninu ẹ̀jẹ awọn enia buburu. |
| 11 |
| Bẹ̃li enia o si wipe, Lõtọ, ère mbẹ fun olododo: lõtọ, on li Ọlọrun ti o nṣe idajọ ni aiye. |
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/psalms/058.mp3
150
58