Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| ỌLỌRUN, iwọ ti ṣa wa tì, iwọ ti tú wa ka, inu rẹ ti bajẹ; tún ara rẹ yipada si wa. |
| 2 |
| Iwọ ti mu ilẹ warìri; iwọ ti fọ ọ: mu fifọ rẹ̀ bọ̀ sipò: nitoriti o nmì. |
| 3 |
| Iwọ ti fi ohun ti o ṣoro hàn awọn enia rẹ: iwọ mu wa mu ọti-waini itagbọngbọn. |
| 4 |
| Iwọ ti fi ọpagun fun awọn ti o bẹ̀ru rẹ, ki a le ma fi i hàn nitori otitọ. |
| 5 |
| Ki a le gbà awọn olufẹ rẹ là; fi ọwọ ọtún rẹ ṣe igbala, ki o si gbohùn mi. |
| 6 |
| Ọlọrun ti sọ̀rọ ninu ìwa-mimọ́ rẹ̀ pe; Emi o yọ̀, emi o pin Ṣekemu, emi o si wọ̀n afonifoji Sukkotu. |
| 7 |
| Ti emi ni Gileadi, ti emi ni Manasse; Efraimu pẹlu li agbara ori mi; Juda li olofin mi; |
| 8 |
| Moabu li ikoko-iwẹsẹ mi; lori Edomu li emi o bọ́ bàta mi si: Filistia ma ho iho ayọ̀ fun mi! |
| 9 |
| Tani yio mu mi wá sinu ilu olodi nì? tani yio sin mi lọ si Edomu? |
| 10 |
| Iwọ ha kọ́, Ọlọrun, ẹniti o ṣa wa tì? ati iwọ, Ọlọrun, ti kò ba ogun wa jade lọ? |
| 11 |
| Fun wa ni iranlọwọ ninu ipọnju: nitori pe asan ni iranlọwọ enia. |
| 12 |
| Nipasẹ Ọlọrun li awa o ṣe akin: nitori on ni yio tẹ̀ awọn ọta wa mọlẹ. |
|
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/psalms/060.mp3
150
60