Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| GBỌ́ ẹkún mi, Ọlọrun; fiye si adura mi. |
| 2 |
| Lati opin aiye wá li emi o kigbe pè ọ, nigbati o rẹ̀ aiya mi, fà mi lọ si apata ti o ga jù mi lọ. |
| 3 |
| Nitori iwọ li o ti nṣe àbo fun mi, ati ile-iṣọ agbara lọwọ ọta nì. |
| 4 |
| Emi o joko ninu agọ rẹ lailai: jẹ ki emi ri àbo ni iyẹ-apa rẹ. |
| 5 |
| Nitoripe iwọ, Ọlọrun, li o ti gbọ́ ẹjẹ́ mi: iwọ ti fi ogún awọn ti o bẹ̀ru orukọ rẹ fun mi. |
| 6 |
| Iwọ o fa ẹmi ọba gùn: ati ọjọ ọdun rẹ̀ bi atiran-diran. |
| 7 |
| On o ma gbe iwaju Ọlọrun lailai; pèse ãnu ati otitọ, ti yio ma ṣe itọju rẹ̀. |
| 8 |
| Bẹ̃li emi o ma kọrin iyìn si orukọ rẹ lailai, ki emi ki o le ma san ẹjẹ́ mi li ojojumọ. |
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/psalms/061.mp3
150
61