Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| ỌLỌRUN, iyìn duro jẹ de ọ ni Sioni: ati si ọ li a o mu ileri ifẹ nì ṣẹ. |
| 2 |
| Iwọ ti ngbọ́ adura, si ọdọ rẹ ni gbogbo enia mbọ̀. |
| 3 |
| Ọ̀ran aiṣedede bori mi: bi o ṣe ti irekọja wa ni, iwọ ni yio wẹ̀ wọn nù kuro. |
| 4 |
| Alabukún-fun li ẹniti iwọ yàn, ti iwọ si mu lati ma sunmọ ọdọ rẹ, ki o le ma gbe inu agbala rẹ wọnni: ore inu ile rẹ yio tẹ́ wa lọrùn, ani ti tempili mimọ́ rẹ. |
| 5 |
| Ohun iyanu nipa ododo ni iwọ fi da wa lohùn, Ọlọrun igbala wa: ẹniti iṣe igbẹkẹle gbogbo opin aiye, ati awọn ti o jina réré si okun. |
| 6 |
| Nipa agbara rẹ̀ ẹniti o fi idi òke nla mulẹ ṣinṣin; ti a fi agbara dì li àmure: |
| 7 |
| Ẹniti o pa ariwo okun mọ́ rọrọ, ariwo riru-omi wọn, ati gìrìgìrì awọn enia. |
| 8 |
| Awọn pẹlu ti ngbe apa ipẹkun mbẹ̀ru nitori àmi rẹ wọnni: iwọ mu ijade owurọ ati ti aṣalẹ yọ̀. |
| 9 |
| Iwọ bẹ aiye wò, o si bomi rin i: iwọ mu u li ọrọ̀, odò Ọlọrun kún fun omi: iwọ pèse ọkàn wọn, nigbati iwọ ti pèse ilẹ bẹ̃. |
| 10 |
| Iwọ fi irinmi si aporo rẹ̀ pipọpìpọ: iwọ si tẹ́ ogulutu rẹ̀: iwọ fi ọwọ òjọ mu ilẹ rẹ̀ rọ̀: iwọ busi hihu rẹ̀. |
| 11 |
| Iwọ fi ore rẹ de ọdun li ade; ọrá nkán ni ipa-ọ̀na rẹ. |
| 12 |
| Papa-tutù aginju nkán: awọn òke kekèke fi ayọ̀ di ara wọn li àmure. |
| 13 |
| Agbo ẹran li a fi wọ̀ pápá-tútù na li aṣọ: afonifoji li a fi ọka bò mọlẹ: nwọn nhó fun ayọ̀, nwọn nkọrin pẹlu. |
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/psalms/065.mp3
150
65