×

Bibeli Mimọ Bible 2012

Saamu 7

1
OLUWA, Ọlọrun mi, iwọ ni mo gbẹkẹ mi le: gbà mi lọwọ gbogbo awọn ti nṣe inunibini si mi, ki o si yọ mi kuro.
2
Ki o má ba fa ọkàn mi ya bi kiniun, a yà a pẹrẹpẹrẹ, nigbati kò si oluranlọwọ.
3
Oluwa, Ọlọrun mi, bi mo ba ṣe eyi, bi ẹ̀ṣẹ ba mbẹ li ọwọ mi;
4
Bi mo ba fi ibi san a fun ẹniti temi tirẹ̀ wà li alafia; (nitõtọ ẹniti nṣe ọta mi li ainidi, emi tilẹ gbà a là:)
5
Jẹ ki ọta ki o ṣe inunibini si ọkàn mi, ki o si mu u; ki o tẹ̀ ẹmi mi mọlẹ, ki o si fi ọlá mi le inu ekuru.
6
Dide Oluwa, ni ibinu rẹ! gbé ara rẹ soke nitori ikannu awọn ọta mi: ki iwọ ki o si jí fun mi si idajọ ti iwọ ti pa li aṣẹ.
7
Bẹ̃ni ijọ awọn enia yio yi ọ ká kiri; njẹ nitori wọn iwọ pada si òke.
8
Oluwa yio ṣe idajọ awọn enia: Oluwa ṣe idajọ mi, gẹgẹ bi ododo mi, ati gẹgẹ bi ìwatitọ inu mi.
9
Jẹ ki ìwa-buburu awọn enia buburu ki o de opin: ṣugbọn mu olotitọ duro: nitoriti Ọlọrun olododo li o ndan aiya ati inu wò.
10
Abo mi mbẹ lọdọ Ọlọrun ti o nṣe igbala olotitọ li aiya.
11
Ọlọrun li onidajọ ododo, Ọlọrun si nbinu si enia buburu lojojumọ:
12
Bi on kò ba yipada, yio si pọ́n idà rẹ̀ mu: o ti fà ọrun rẹ̀ le na, o ti mura rẹ̀ silẹ.
13
O si ti pèse elo ikú silẹ fun u; o ti ṣe awọn ọfa rẹ̀ ni oniná.
14
Kiyesi i, o nrọbi ẹ̀ṣẹ, o si loyun ìwa-ìka, o si bí eké jade.
15
O ti wà ọ̀fin, o gbẹ́ ẹ, o si bọ́ sinu iho ti on na wà.
16
Ìwa-ika rẹ̀ yio si pada si ori ara rẹ̀, ati ìwa-agbara rẹ̀ yio si sọ̀kalẹ bọ̀ si atari ara rẹ̀.
17
Emi o yìn Oluwa gẹgẹ bi ododo rẹ̀: emi o si kọrin iyìn si orukọ Oluwa Ọga-ogo julọ.
Yoruba Bible 2012
Yoruba Bible Crowther Version The Bible Society of Nigeria, 2012
:
Fipamọ Awọn akọsilẹ