|
| 1 |
|
| OLUWA, iwọ ni mo gbẹkẹ mi le: lai máṣe jẹ ki a dãmu mi. |
|
| 2 |
|
| Gbà mi nipa ododo rẹ, ki o si mu mi yọ̀: dẹ eti rẹ si mi, ki o si gbà mi. |
|
| 3 |
|
| Iwọ ni ki o ṣe ibujoko apata mi, nibiti emi o gbe ma rè nigbagbogbo: iwọ ti paṣẹ lati gbà mi; nitori iwọ li apata ati odi agbara mi. |
|
| 4 |
|
| Gbà mi, Ọlọrun mi, li ọwọ awọn enia buburu, li ọwọ alaiṣododo ati ìka ọkunrin. |
|
| 5 |
|
| Nitori iwọ ni ireti mi, Oluwa Ọlọrun; iwọ ni igbẹkẹle mi lati igba ewe mi. |
|
| 6 |
|
| Ọwọ rẹ li a ti fi gbé mi duro lati inu wá: iwọ li ẹniti o mu mi jade lati inu iya mi wá: nipasẹ rẹ ni iyìn mi wà nigbagbogbo. |
|
| 7 |
|
| Emi dabi ẹni-iyanu fun ọ̀pọlọpọ enia, ṣugbọn iwọ li àbo mi ti o lagbara. |
|
| 8 |
|
| Jẹ ki ẹnu mi ki o kún fun iyìn rẹ ati fun ọlá rẹ li ọjọ gbogbo. |
|
| 9 |
|
| Máṣe ṣa mi ti ni ìgba ogbó; máṣe kọ̀ mi silẹ nigbati agbara mi ba yẹ̀. |
|
| 10 |
|
| Nitori awọn ọta mi nsọ̀rọ si mi; awọn ti nṣọ ọkàn mi si gbimọ̀ pọ̀. |
|
| 11 |
|
| Nwọn wipe, Ọlọrun ti kọ̀ ọ silẹ: ẹ lepa ki ẹ si mu u; nitori ti kò si ẹniti yio gbà a. |
|
| 12 |
|
| Ọlọrun, máṣe jina si mi: Ọlọrun mi, yara si iranlọwọ mi. |
|
| 13 |
|
| Jẹ ki nwọn ki o dãmu, ki a si run awọn ti nṣe ọta ọkàn mi, ki a si fi ẹ̀gan ati àbuku bo awọn ti nwá ifarapa mi. |
|
| 14 |
|
| Ṣugbọn emi o ma reti nigbagbogbo, emi o si ma fi iyìn kún iyìn rẹ. |
|
| 15 |
|
| Ẹnu mi yio ma fi ododo rẹ ati igbala rẹ hàn li ọjọ gbogbo; emi kò sa mọ̀ iye rẹ̀. |
|
| 16 |
|
| Emi o wá li agbara Oluwa Ọlọrun; emi o ma da ọ̀rọ ododo rẹ sọ, ani tirẹ nikan. |
|
| 17 |
|
| Ọlọrun, iwọ ti kọ́ mi lati igba ewe mi wá: ati di isisiyi li emi ti nsọ̀rọ iṣẹ iyanu rẹ. |
|
| 18 |
|
| Pẹlupẹlu, nigbati emi di arugbo tan ti mo hewu, Ọlọrun máṣe kọ̀ mi; titi emi o fi fi ipá rẹ hàn fun iran yi, ati agbara rẹ fun gbogbo awọn ara ẹ̀hin. |
|
| 19 |
|
| Ọlọrun ododo rẹ ga jọjọ pẹlu, ẹniti o ti nṣe nkan nla: Ọlọrun, tali o dabi iwọ! |
|
| 20 |
|
| Iwọ ti o fi iṣẹ nla ati kikan hàn mi, ni yio si tun mi ji, yio si tun mu mi sọ si òke lati ọgbun ilẹ wá. |
|
| 21 |
|
| Iwọ o sọ ọlá mi di pupọ̀, iwọ o si tù mi ninu niha gbogbo. |
|
| 22 |
|
| Emi o si fi ohun-elo orin yìn ọ pẹlu, ani otitọ rẹ, Ọlọrun mi: iwọ li emi o ma fi duru kọrin si, iwọ Ẹni-Mimọ́ Israeli. |
|
| 23 |
|
| Ete mi yio yọ̀ gidigidi, nigbati mo ba nkọrin si ọ: ati ọkàn mi, ti iwọ ti rapada. |
|
| 24 |
|
| Ahọn mi pẹlu yio si ma sọ̀rọ ododo rẹ titi li ọjọ gbogbo: nitoriti nwọn dãmu, a si doju ti awọn tí nwá ifarapa mi. |
|
|
|
|