|
| 1 |
|
| NITÕTỌ Ọlọrun ṣeun fun Israeli, fun iru awọn ti iṣe alaiya mimọ́. |
|
| 2 |
|
| Ṣugbọn bi o ṣe ti emi ni, ẹsẹ mi fẹrẹ yẹ̀ tan; ìrin mi fẹrẹ yọ́ tan. |
|
| 3 |
|
| Nitori ti emi ṣe ilara si awọn aṣe-fefe, nigbati mo ri alafia awọn enia buburu. |
|
| 4 |
|
| Nitoriti kò si irora ninu ikú wọn: agbara wọn si pọ̀. |
|
| 5 |
|
| Nwọn kò ni ipin ninu iyọnu enia; bẹ̃ni a kò si wahala wọn pẹlu ẹlomiran. |
|
| 6 |
|
| Nitorina ni igberaga ṣe ká wọn lọrun bi ẹ̀wọn ọṣọ́; ìwa-ipa bò wọn mọlẹ bi aṣọ. |
|
| 7 |
|
| Oju wọn yọ jade fun isanra: nwọn ní jù bi ọkàn wọn ti nfẹ lọ. |
|
| 8 |
|
| Nwọn nṣẹsin, nwọn si nsọ̀rọ buburu niti inilara: nwọn nsọ̀rọ lati ibi giga. |
|
| 9 |
|
| Nwọn gbé ẹnu wọn le ọrun, ahọn wọn si nrìn ilẹ já. |
|
| 10 |
|
| Nitorina li awọn enia rẹ̀ ṣe yipada si ihin: ọ̀pọlọpọ omi li a si npọn jade fun wọn. |
|
| 11 |
|
| Nwọn si wipe, Ọlọrun ti ṣe mọ̀? ìmọ ha wà ninu Ọga-ogo? |
|
| 12 |
|
| Kiyesi i, awọn wọnyi li alaìwa-bi-ọlọrun, ẹniti aiye nsan, nwọn npọ̀ li ọrọ̀. |
|
| 13 |
|
| Nitõtọ li asan ni mo wẹ̀ aiya mi mọ́, ti mo si wẹ̀ ọwọ mi li ailẹ̀ṣẹ. |
|
| 14 |
|
| Nitoripe ni gbogbo ọjọ li a nyọ mi lẹnu, a si nnà mi li orowurọ. |
|
| 15 |
|
| Bi emi ba pe, emi o fọ̀ bayi: kiyesi i, emi o ṣẹ̀ si iran awọn ọmọ rẹ. |
|
| 16 |
|
| Nigbati mo rò lati mọ̀ eyi, o ṣoro li oju mi. |
|
| 17 |
|
| Titi mo fi lọ sinu ibi-mimọ́ Ọlọrun; nigbana ni mo mọ̀ igbẹhin wọn. |
|
| 18 |
|
| Nitõtọ iwọ gbé wọn ka ibi yiyọ́: iwọ tì wọn ṣubu sinu iparun. |
|
| 19 |
|
| Bawo li a ti mu wọn lọ sinu idahoro yi, bi ẹnipe ni iṣẹju kan! ibẹru li a fi nrun wọn patapata. |
|
| 20 |
|
| Bi igbati ẹnikan ba ji li oju alá; bẹ̃ni Oluwa, nigbati iwọ ba ji, iwọ o ṣe àbuku àworan wọn. |
|
| 21 |
|
| Bayi ni inu mi bajẹ, ẹgún si gun mi li ọkàn mi. |
|
| 22 |
|
| Bẹ̃ni mo ṣiwere, ti emi kò si mọ̀ nkan; mo dabi ẹranko niwaju rẹ. |
|
| 23 |
|
| Ṣugbọn emi wà pẹlu rẹ nigbagbogbo: iwọ li o ti di ọwọ ọtún mi mu. |
|
| 24 |
|
| Iwọ o fi ìmọ rẹ tọ́ mi li ọ̀na, ati nigbẹhin iwọ o gbà mi sinu ogo. |
|
| 25 |
|
| Tani mo ni li ọrun bikoṣe iwọ? kò si si ohun ti mo fẹ li aiye pẹlu rẹ. |
|
| 26 |
|
| Ẹran-ara mi ati aiya mi di ãrẹ̀ tan: ṣugbọn Ọlọrun ni apata aiya mi, ati ipin mi lailai. |
|
| 27 |
|
| Sa wò o, awọn ti o jina si ọ yio ṣegbe: iwọ ti pa gbogbo wọn run ti nṣe àgbere kiri kuro lọdọ rẹ. |
|
| 28 |
|
| Ṣugbọn o dara fun mi lati sunmọ Ọlọrun: emi ti gbẹkẹ mi le Oluwa Ọlọrun, ki emi ki o le ma sọ̀rọ iṣẹ rẹ gbogbo. |
|
|
|
|