Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| ỌLỌRUN, awọn keferi wá si ilẹ-ini rẹ; tempili mimọ́ rẹ ni nwọn sọ di ẽri; nwọn sọ Jerusalemu di òkiti-alapa. |
| 2 |
| Okú awọn iranṣẹ rẹ ni nwọn fi fun ẹiyẹ oju-ọrun li onjẹ, ẹran-ara awọn enia mimọ́ rẹ fun ẹranko ilẹ. |
| 3 |
| Ẹ̀jẹ wọn ni nwọn ta silẹ bi omi yi Jerusalemu ka; kò si si ẹniti yio gbé wọn sìn. |
| 4 |
| Awa di ẹ̀gan si awọn aladugbo wa, ẹlẹya ati iyọṣuti si awọn ti o yi wa ka. |
| 5 |
| Yio ti pẹ to, Oluwa? iwọ o binu titi lailai? owú rẹ yio ha ma jó bi iná? |
| 6 |
| Dà ibinu rẹ si ori awọn keferi ti kò mọ̀ ọ, ati si ori awọn ijọba ti kò kepè orukọ rẹ. |
| 7 |
| Nitori ti nwọn ti mu Jakobu jẹ, nwọn si sọ ibujoko rẹ̀ di ahoro. |
| 8 |
| Máṣe ranti ẹ̀ṣẹ awọn aṣaju wa si wa: jẹ ki iyọnu rẹ ki o ṣaju wa nisisiyi: nitori ti a rẹ̀ wa silẹ gidigidi. |
| 9 |
| Ràn wa lọwọ, Ọlọrun igbala wa, nitori ogo orukọ rẹ: ki o si gbà wa, ki o si wẹ̀ ẹ̀ṣẹ wa nù, nitori orukọ rẹ. |
| 10 |
| Nitori kili awọn keferi yio ṣe wipe, Nibo li Ọlọrun wọn wà? jẹ ki a mọ̀ igbẹsan ẹ̀jẹ awọn iranṣẹ rẹ ti a ta silẹ loju wa ninu awọn keferi. |
| 11 |
| Jẹ ki imi-ẹdun onde nì ki o wá siwaju rẹ: gẹgẹ bi titobi agbara rẹ, iwọ dá awọn ti a yàn si pipa silẹ: |
| 12 |
| Ki o si san ẹ̀gan wọn nigba meje fun awọn aladugbo wa li aiya wọn, nipa eyiti nwọn ngàn ọ, Oluwa. |
| 13 |
| Bẹ̃li awa enia rẹ ati agutan papa rẹ, yio ma fi ọpẹ fun ọ lailai, awa o ma fi iyìn rẹ hàn lati irandiran. |
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/psalms/079.mp3
150
79