Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| OLUWA, iwọ ti nṣe oju rere si ilẹ rẹ: iwọ ti mu igbekun Jakobu pada bọ̀. |
| 2 |
| Iwọ ti dari aiṣedede awọn enia rẹ jì, iwọ ti bò gbogbo ẹ̀ṣẹ wọn mọlẹ. |
| 3 |
| Iwọ ti mu gbogbo ibinu rẹ kuro: iwọ ti yipada kuro ninu gbigbona ibinu rẹ. |
| 4 |
| Yi wa pada, Ọlọrun igbala wa, ki o si mu ibinu rẹ si wa ki o dá. |
| 5 |
| Iwọ o binu si wa titi lai? iwọ o fà ibinu rẹ jade lati irandiran? |
| 6 |
| Iwọ kì yio tun mu wa sọji: ki awọn enia rẹ ki o ma yọ̀ ninu rẹ? |
| 7 |
| Oluwa fi ãnu rẹ hàn fun wa, ki o si fun wa ni igbala rẹ. |
| 8 |
| Emi o gbọ́ bi Ọlọrun Oluwa yio ti wi: nitoriti yio sọ alafia si awọn enia rẹ̀, ati si awọn enia mimọ́ rẹ̀: ṣugbọn ki nwọn ki o má tun pada si were. |
| 9 |
| Nitõtọ igbala rẹ̀ sunmọ́ awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀; ki ogo ki o le ma gbé ilẹ wa. |
| 10 |
| Ãnu ati otitọ padera; ododo ati alafia ti fi ẹnu kò ara wọn li ẹnu. |
| 11 |
| Otitọ yio rú jade lati ilẹ wá: ododo yio si bojuwò ilẹ lati ọrun wá. |
| 12 |
| Nitõtọ Oluwa yio funni li eyi ti o dara; ilẹ wa yio si ma mu asunkun rẹ̀ wá. |
| 13 |
| Ododo yio ṣãju rẹ̀; yio si fi ipasẹ rẹ̀ ṣe ọ̀na. |
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/psalms/085.mp3
150
85