Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| OLUWA Ọlọrun igbala mi, emi nkigbe lọsan ati loru niwaju rẹ. |
| 2 |
| Jẹ ki adura mi ki o wá si iwaju rẹ: dẹ eti rẹ silẹ si igbe mi. |
| 3 |
| Nitori ti ọkàn mi kún fun ipọnju, ẹmi mi si sunmọ isa-okú. |
| 4 |
| A kà mi pẹlu kún awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò: emi dabi ọkunrin ti kò ni ipá. |
| 5 |
| Ẹniti a kọ̀ silẹ lãrin awọn okú, bi awọn ẹni pipa ti o dubulẹ ni isa-okú, ẹniti iwọ kò ranti mọ́: a si ke wọn kuro nipa ọwọ rẹ. |
| 6 |
| Iwọ ti fi mi le ibi isalẹ ti o jìn julọ, ninu okunkun, ninu ọgbun. |
| 7 |
| Ibinu rẹ lẹ̀ mọ mi lara kikan, iwọ si ti fi riru omi rẹ gbogbo ba mi ja. |
| 8 |
| Iwọ ti mu awọn ojulumọ mi jina si mi; iwọ si sọ mi di irira si wọn; a se mi mọ́, emi kò le jade. |
| 9 |
| Oju mi nkãnu nitori ipọnju: Oluwa, emi ti npè ọ lojojumọ, emi si ti nawọ mi si ọ. |
| 10 |
| Iwọ o fi iṣẹ iyanu rẹ hàn fun okú bi? awọn okú yio ha dide ki nwọn si ma yìn ọ bi? |
| 11 |
| A o ha fi iṣeun ifẹ rẹ hàn ni isà-òkú bi? tabi otitọ rẹ ninu iparun? |
| 12 |
| A ha le mọ̀ iṣẹ iyanu rẹ li okunkun bi? ati ododo rẹ ni ilẹ igbagbe? |
| 13 |
| Ṣugbọn iwọ ni mo kigbe si, Oluwa; ati ni kutukutu owurọ li adura mi yio ṣaju rẹ. |
| 14 |
| Oluwa, ẽṣe ti iwọ fi ṣa ọkàn mi tì? ẽṣe ti iwọ fi pa oju rẹ mọ́ kuro lọdọ mi? |
| 15 |
| Iṣẹ́ nṣẹ mi, emi mura ati kú lati igba ewe mi wá: nigbati ẹ̀ru rẹ ba mbà mi, emi di gbéregbère. |
| 16 |
| Ifẹju ibinu rẹ kọja lara mi; ìbẹru rẹ ti ke mi kuro. |
| 17 |
| Nwọn wá yi mi ka li ọjọ gbogbo bi omi: nwọn yi mi kakiri tan. |
| 18 |
| Olufẹ ati ọrẹ ni iwọ mu jina si mi, ati awọn ojulumọ mi ninu okunkun. |
|
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/psalms/088.mp3
150
88