|
| 1 |
|
| EMI o ma kọrin ãnu Oluwa lailai: ẹnu mi li emi o ma fi fi otitọ rẹ hàn lati irandiran. |
|
| 2 |
|
| Nitori ti emi ti wipe, A o gbé ãnu ró soke lailai: otitọ rẹ ni iwọ o gbé kalẹ li ọrun. |
|
| 3 |
|
| Emi ti bá ayànfẹ mi da majẹmu, emi ti bura fun Dafidi, iranṣẹ mi, |
|
| 4 |
|
| Irú-ọmọ rẹ li emi o gbé kalẹ lailai, emi o si ma gbé itẹ́ rẹ ró lati irandiran, |
|
| 5 |
|
| Ọrun yio si ma yìn iṣẹ-iyanu rẹ, Oluwa, otitọ rẹ pẹlu ninu ijọ enia mimọ́ rẹ. |
|
| 6 |
|
| Nitori pe, tali o wà li ọrun ti a le fi wé Oluwa? tani ninu awọn ọmọ alagbara, ti a le fi wé Oluwa? |
|
| 7 |
|
| Ọlọrun li o ni ìbẹru gidigidi ni ijọ enia mimọ́, o si ni ibuyìn-fun lati ọdọ gbogbo awọn ti o yi i ká. |
|
| 8 |
|
| Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, tani Oluwa alagbara bi iwọ? tabi bi otitọ rẹ ti o yi ọ ká. |
|
| 9 |
|
| Iwọ li o jọba ibinu okun; nigbati riru omi rẹ̀ dide, iwọ mu u pa rọrọ. |
|
| 10 |
|
| Iwọ li o ti ya Rahabu pẹrẹ-pẹrẹ bi ẹniti a pa; iwọ ti fi apa ọwọ́ agbara rẹ tú awọn ọtá rẹ ká. |
|
| 11 |
|
| Ọrun ni tirẹ, aiye pẹlu ni tirẹ: aiye ati ẹ̀kun rẹ̀, iwọ li o ti ṣe ipilẹ wọn. |
|
| 12 |
|
| Ariwa ati gusù iwọ li o ti da wọn: Taboru ati Hermoni yio ma yọ̀ li orukọ rẹ. |
|
| 13 |
|
| Iwọ ni apá agbara: agbara li ọwọ́ rẹ, giga li ọwọ ọtún rẹ. |
|
| 14 |
|
| Otitọ ati idajọ ni ibujoko itẹ́ rẹ: ãnu ati otitọ ni yio ma lọ siwaju rẹ. |
|
| 15 |
|
| Ibukún ni fun awọn enia ti o mọ̀ ohùn ayọ̀ nì: Oluwa, nwọn o ma rìn ni imọlẹ oju rẹ. |
|
| 16 |
|
| Li orukọ rẹ ni nwọn o ma yọ̀ li ọjọ gbogbo: ati ninu ododo rẹ li a o ma gbé wọn leke. |
|
| 17 |
|
| Nitori iwọ li ogo agbara wọn: ati ninu ore ojurere rẹ li a o gbé iwo wa soke, |
|
| 18 |
|
| Nitori Oluwa li asà wa: Ẹni-Mimọ́ Israeli li ọba wa. |
|
| 19 |
|
| Nigbana ni iwọ sọ li oju iran fun ayanfẹ rẹ, o si wipe, Emi ti gbé iranlọwọ ru ẹni-alagbara; emi ti gbé ẹnikan leke ti a yàn ninu awọn enia. |
|
| 20 |
|
| Emi ti ri Dafidi, iranṣẹ mi; ororo mi mimọ́ ni mo ta si i li ori: |
|
| 21 |
|
| Nipasẹ ẹniti a o fi ọwọ mi mulẹ: apá mi pẹlu yio ma mu u li ara le. |
|
| 22 |
|
| Ọtá kì yio bère lọdọ rẹ̀; bẹ̃ni awọn ọmọ iwà-buburu kì yio pọ́n ọ loju. |
|
| 23 |
|
| Emi o si lu awọn ọta rẹ̀ bolẹ niwaju rẹ̀, emi o si yọ awọn ti o korira rẹ̀ lẹnu. |
|
| 24 |
|
| Ṣugbọn otitọ mi ati ãnu mi yio wà pẹlu rẹ̀; ati li orukọ mi li a o gbé iwo rẹ̀ soke. |
|
| 25 |
|
| Emi o gbé ọwọ rẹ̀ le okun, ati ọwọ ọtún rẹ̀ le odò nla nì. |
|
| 26 |
|
| On o kigbe pè mi pe, Iwọ ni baba mi, Ọlọrun mi, ati apata igbala mi. |
|
| 27 |
|
| Emi o si ṣe e li akọbi, Ẹni-giga jù awọn ọba aiye lọ. |
|
| 28 |
|
| Ãnu mi li emi o pamọ́ fun u lailai, ati majẹmu mi yio si ba a duro ṣinṣin. |
|
| 29 |
|
| Irú-ọmọ rẹ̀ pẹlu li emi o mu pẹ titi, ati itẹ́ rẹ̀ bi ọjọ ọrun. |
|
| 30 |
|
| Bi awọn ọmọ rẹ̀ ba kọ̀ ofin mi silẹ, ti nwọn kò si rìn nipa idajọ mi; |
|
| 31 |
|
| Bi nwọn ba bá ilana mi jẹ, ti nwọn kò si pa ofin mi mọ́, |
|
| 32 |
|
| Nigbana li emi o fi ọgọ bẹ irekọja wọn wò, ati ẹ̀ṣẹ wọn pẹlu ìna. |
|
| 33 |
|
| Ṣugbọn iṣeun-ifẹ mi li emi kì yio gbà lọwọ rẹ̀, bẹ̃li emi kì yio jẹ ki otitọ mi ki o yẹ̀. |
|
| 34 |
|
| Majẹmu mi li emi kì yio dà, bẹ̃li emi kì yio yi ohun ti o ti ète mi jade pada. |
|
| 35 |
|
| Lẹrinkan ni mo ti fi ìwa-mimọ́ mi bura pe, emi kì yio purọ fun Dafidi. |
|
| 36 |
|
| Iru-ọmọ rẹ̀ yio duro titi lailai, ati itẹ́ rẹ̀ bi õrun niwaju mi. |
|
| 37 |
|
| A o fi idi rẹ̀ mulẹ lailai bi òṣupa, ati bi ẹlẹri otitọ li ọrun. |
|
| 38 |
|
| Ṣugbọn iwọ ti ṣa tì, iwọ si korira, iwọ ti binu si Ẹni-ororo rẹ. |
|
| 39 |
|
| Iwọ ti sọ majẹmu iranṣẹ rẹ di ofo: iwọ ti sọ ade rẹ̀ si ilẹ. |
|
| 40 |
|
| Iwọ ti fa ọgba rẹ̀ gbogbo ya: iwọ ti mu ilu-olodi rẹ̀ di ahoro. |
|
| 41 |
|
| Gbogbo awọn ti nkọja lọ li ọ̀na nfi ṣe ijẹ: on si di ẹ̀gan fun awọn aladugbo rẹ̀. |
|
| 42 |
|
| Iwọ ti gbé ọwọ ọtún awọn ọta rẹ̀ soke; iwọ mu gbogbo awọn ọta rẹ̀ yọ̀. |
|
| 43 |
|
| Iwọ si ti yi oju idà rẹ̀ pada pẹlu, iwọ kò si mu u duro li oju ogun. |
|
| 44 |
|
| Iwọ ti mu ogo rẹ̀ tẹ́, iwọ si wọ́ itẹ́ rẹ̀ silẹ-yilẹ. |
|
| 45 |
|
| Ọjọ ewe rẹ̀ ni iwọ ke kuru; iwọ fi itìju bò o. |
|
| 46 |
|
| Yio ti pẹ to, Oluwa? iwọ o pa ara rẹ mọ́ lailai? ibinu rẹ yio ha jo bi iná bi? |
|
| 47 |
|
| Ranti bi ọjọ mi ti kuru to; ẽse ti iwọ ha da gbogbo enia lasan? |
|
| 48 |
|
| Ọkunrin wo li o wà lãye, ti kì yio ri ikú? ti yio gbà ọkàn rẹ̀ lọwọ isa-okú. |
|
| 49 |
|
| Oluwa, nibo ni iṣeun-ifẹ rẹ atijọ wà, ti iwọ bura fun Dafidi ninu otitọ rẹ? |
|
| 50 |
|
| Oluwa, ranti ẹ̀gan awọn iranṣẹ rẹ, ti emi nrù li aiya mi lati ọdọ gbogbo ọ̀pọ enia. |
|
| 51 |
|
| Ti awọn ọta rẹ fi kẹgàn, Oluwa: ti nwọn fi ngàn ipasẹ Ẹni-ororo rẹ. |
|
| 52 |
|
| Olubukún ni Oluwa si i titi lailai. Amin ati Amin. |
|
|
|
|