|
| 1 |
|
| EMI o fi gbogbo aiya mi yìn Oluwa: emi o fi gbogbo iṣẹ iyanu rẹ hàn. |
|
| 2 |
|
| Emi o yọ̀, emi o si ṣe inu-didùn ninu rẹ, emi o si kọrin iyìn si orukọ rẹ, iwọ Ọga-ogo julọ. |
|
| 3 |
|
| Nigbati awọn ọta mi ba pẹhinda, nwọn o ṣubu, nwọn o si ṣegbe ni iwaju rẹ. |
|
| 4 |
|
| Nitori iwọ li o ti mu idajọ mi ati idi ọ̀ran mi duro; iwọ li o joko lori itẹ́, ti o nṣe idajọ ododo. |
|
| 5 |
|
| Iwọ ba awọn orilẹ-ède wi, iwọ pa awọn enia buburu run, iwọ pa orukọ wọn rẹ́ lai ati lailai. |
|
| 6 |
|
| Niti ọta, iparun wọn pari tan lailai: iwọ li o si ti run ilu wọnni; iranti wọn si ti ṣegbe pẹlu wọn. |
|
| 7 |
|
| Ṣugbọn Oluwa yio wà titi lailai: o ti tẹ́ itẹ́ rẹ̀ silẹ fun idajọ. |
|
| 8 |
|
| On o si ṣe idajọ aiye li ododo, yio ṣe idajọ fun awọn enia li otitọ ìwa. |
|
| 9 |
|
| Oluwa ni yio ṣe àbo awọn ẹni-inilara, àbo ni igba ipọnju. |
|
| 10 |
|
| Awọn ti o si mọ̀ orukọ rẹ o gbẹkẹ le ọ: nitori iwọ, Oluwa, kò ti ikọ̀ awọn ti nṣe afẹri rẹ silẹ. |
|
| 11 |
|
| Ẹ kọrin iyìn si Oluwa, ti o joko ni Sioni: ẹ fi iṣẹ rẹ̀ hàn ninu awọn enia. |
|
| 12 |
|
| Nigbati o wadi ẹjọ-ẹ̀jẹ, o ranti wọn: on kò si gbagbe ẹkún awọn olupọnju. |
|
| 13 |
|
| Ṣãnu fun mi, Oluwa; rò iṣẹ́ ti emi nṣẹ́ lọwọ awọn ti o korira mi, iwọ ti o gbé ori mi soke kuro li ẹnu-ọ̀na ikú. |
|
| 14 |
|
| Ki emi ki o le ma fi gbogbo iyìn rẹ hàn li ẹnu-ọ̀na ọmọbinrin Sioni, emi o ma yọ̀ ni igbala rẹ. |
|
| 15 |
|
| Awọn orilẹ-ède jìn sinu ọ̀fin ti nwọn wà: ninu àwọn ti nwọn dẹ silẹ li ẹsẹ ara wọn kọ́. |
|
| 16 |
|
| A mọ̀ Oluwa, nipa idajọ ti o nṣe: nipa iṣẹ ọwọ enia buburu li a fi ndẹkùn mu u. |
|
| 17 |
|
| Ori awọn enia buburu li a o dà si ọrun apadi, ati gbogbo orilẹ-ède ti o gbagbe Ọlọrun. |
|
| 18 |
|
| Nitori pe a kì yio gbagbe awọn alaini lailai: abá awọn talaka kì yio ṣegbe lailai. |
|
| 19 |
|
| Oluwa, dide; máṣe jẹ ki enia ki o bori: jẹ ki a ṣe idajọ awọn orilẹ-ède niwaju rẹ. |
|
| 20 |
|
| Dẹru ba wọn, Oluwa: ki awọn orilẹ-ède ki o le mọ̀ ara wọn pe, enia ṣa ni nwọn. |
|
|
|
|