Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| ẸNITI o joko ni ibi ìkọkọ Ọga-ogo ni yio ma gbe abẹ ojiji Olodumare. |
| 2 |
| Emi o wi fun Ọlọrun pe, Iwọ li àbo ati odi mi; Ọlọrun mi, ẹniti emi gbẹkẹle. |
| 3 |
| Nitõtọ on o gbà ọ ninu ikẹkun awọn pẹyẹpẹyẹ, ati ninu àjakalẹ-àrun buburu. |
| 4 |
| Yio fi iyẹ́ rẹ̀ bò ọ, abẹ iyẹ́-apa rẹ̀ ni iwọ o si gbẹkẹle: otitọ rẹ̀ ni yio ṣe asà ati apata rẹ. |
| 5 |
| Iwọ kì yio bẹ̀ru nitori ẹ̀ru oru; tabi fun ọfa ti nfo li ọsán; |
| 6 |
| Tabi fun àjakalẹ-àrun ti nrìn kiri li okunkun, tabi fun iparun ti nrun-ni li ọsángangan. |
| 7 |
| Ẹgbẹrun yio ṣubu li ẹgbẹ rẹ, ati ẹgbarun li apa ọtún rẹ: ṣugbọn kì yio sunmọ ọdọ rẹ. |
| 8 |
| Kiki oju rẹ ni iwọ o ma fi ri, ti o si ma fi wo ère awọn enia buburu. |
| 9 |
| Nitori iwọ, Oluwa, ni iṣe ãbo mi, iwọ ti fi Ọga-ogo ṣe ibugbe rẹ. |
| 10 |
| Buburu kan kì yio ṣubu lu ọ, bẹ̃li arunkarun kì yio sunmọ ile rẹ. |
| 11 |
| Nitori ti yio fi aṣẹ fun awọn angeli rẹ̀ nitori rẹ, lati pa ọ mọ́ li ọ̀na rẹ gbogbo. |
| 12 |
| Nwọn o gbé ọ soke li ọwọ́ wọn, ki iwọ ki o má ba fi ẹṣẹ rẹ gbun okuta. |
| 13 |
| Iwọ o kọja lori kiniun ati pamọlẹ: ẹgbọrọ kiniun ati ejò-nla ni iwọ o fi ẹsẹ tẹ̀-mọlẹ. |
| 14 |
| Nitori ti o fẹ ifẹ rẹ̀ si mi, nitorina li emi o ṣe gbà a: emi o gbé e leke, nitori ti o mọ̀ orukọ mi. |
| 15 |
| On o pè orukọ mi, emi o si da a lohùn: emi o pẹlu rẹ̀ ninu ipọnju, emi o gbà a, emi o si bu ọlá fun u. |
| 16 |
| Ẹmi gigun li emi o fi tẹ́ ẹ lọrun, emi o si fi igbala mi hàn a. |
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/psalms/091.mp3
150
91