Nígbà náà ni Mósè sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ rántí ọjọ́ òní, ọjọ́ ti ẹ jáde kúrò ni ilẹ́ Éjíbítì, kúrò ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin ti ń ṣe ẹrú, nítorí OLÚWA mú un yín jáde kúrò ni inú rẹ̀ pẹ̀lú ọwọ́ agbára. Ẹ má se jẹ ohunkóhun tí ó ni ìwúkàrà nínú.
Ní ìgbà tí Ọlọ́run mú un yín jáde wá sí ilẹ̀ ẹ Kénánì, Hítì, Ámórì, Hífì àti ilẹ̀ àwọn Jébúsì; ilẹ̀ tí ó ti ṣe ìlérí láti fi fún àwọn baba ńlá yín, ilẹ̀ tí ń sàn fún wàrà àti oyin, ẹ ni láti pa ìsìn yìí mọ́ ní oṣù yìí.
Ṣiṣe èyí yóò wà fún àmì ní ọwọ́ rẹ, àti bí ìránlétí ni iwájú orí rẹ tí yóò máa ran ọ létí òfin OLÚWA ní ẹnu rẹ. Nítorí OLÚWA mú ọ jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá rẹ̀.
Ìwọ yóò fi ọ̀dọ́ àgùntàn ra àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ padà, ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá rà á padà, ǹjẹ́ kí ìwọ ṣẹ́ ẹ ní ọrùn, gbogbo àkọ́bí ọkùnrin ni kí ìwọ kí ó rà padà,
“Yóò sí ṣe ní àwọn ọjọ́ tí ń bọ̀, ní ìgbà tí àwọn ọmọ yín yóò béèrè lọ́wọ́ yín ‘Kí ni èyí túmọ̀ sí?’ Kí ìwọ kí ó sọ fún wọn pé, ‘Pẹ̀lú ọwọ́ agbára ní OLÚWA fi mú wa jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì, kúrò ní oko ẹrú.
Ní ìgbà ti Fáráò ṣe oríkunkun, ti ó kọ̀ láti jẹ́ kí a lọ, OLÚWA pa gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Éjíbítì, àti ènìyàn àti ẹranko. Ìdí èyí ni àwa fi ń fi gbogbo àkọ́bí tí í ṣe akọ rúbọ sí OLÚWA láti fi ṣe ìràpadà fún àwọn àkọ́bí wa ọkùnrin.’
Ní ìgbà tí Fáráò jẹ́ kí àwọn ènìyàn ó lọ, Ọlọ́run kò mú wọn tọ ojú ọ̀nà ti ó la orílẹ̀ èdè àwọn Fílístínì kọjá, bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà náà kúrú. Nítorí Ọlọ́run sọ pé, “Bí wọ́n bá dojú kọ ogun, wọ́n lè yí ọkàn wọn padà kí wọ́n padà sí ilẹ̀ Éjíbítì.”
Mósè kó egungun Jósẹ́fù pẹ̀lú rẹ̀ nítorí Jósẹ́fù tí mú kí àwọn ọmọ Isírẹ́lì búra. Ó ti wí pé, “Dájúdájú Ọlọ́run yóò dìde fún ìrànlọ́wọ́ yín ẹ sì gbọdọ̀ kó egungun mi lọ pẹ̀lú yín kúrò níhìnín yìí.”
OLÚWA sì ń lọ níwájú wọn, nínú òpó ìkùùkuu ní ọ̀san láti máa ṣe amọ̀nà wọn àti ní òru nínú òpó iná láti máa tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn, kí wọn lè máa lọ nínú ìrìnàjò wọn ní tọ̀sán tòru.