Jẹ́tírò, àlùfáà Mídíánì, àna Mósè, gbọ́ gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún Mósè àti fún Ísírẹ́lì àwọn ènìyàn rẹ̀, àti bí OLÚWA ti mú àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì jáde láti Éjíbítì wá.
Mósè sọ fún àna rẹ̀ nípa ohun gbogbo ti OLÚWA tí se sí Fáráò àti àwọn ará Éjíbítì nítorí Ísírẹ́lì. Ó sọ nípa gbogbo ìṣòro tí wọn bá pàdé ní ọ̀nà wọn àti bí OLÚWA ti gbà wọ́n là.
Jẹ́tírò sì wí pé, “Ìyìn ni fún OLÚWA, ẹni tí ó gba yín là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Éjíbítì àti lọ́wọ́ Fáráò, ẹni tí ó sì gbà àwọn ènìyàn là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Éjíbítì.
Nígbà tí àna Mósè rí bí àkókò ti èyí ń gba ti pọ̀ tó àti ti àwọn ènìyàn ti ń dúró pẹ́ tó, ó wí pé, “Kí ni èyí tí ìwọ ń se sí àwọn ènìyàn? Èéṣe ti ìwọ nìkan jòkóò gẹ́gẹ́ bí adájọ́, nígbà tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí dúró yí ọ ká láti òwúrọ̀ di ìrọ̀lẹ́?”
Nísinsìnyìí, fetísílẹ̀ sí mi, èmi yóò sì gbà ọ́ ni ìmọ̀ràn, Ọlọ́run yóò sì wà pẹ̀lú rẹ. Ìwọ gbọdọ̀ jẹ́ aṣojú àwọn ènìyàn wọ̀nyí níwájú Ọlọ́run, ìwọ yóò sì mú èdè àìyedè wá sí iwájú rẹ̀.
Sà àwọn tí ó kún ojú òṣùwọ̀n nínú gbogbo àwọn ènìyàn: àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run, ti wọ́n jẹ́ olóòótọ́, tí wọ́n kórìíra ìrẹ́jẹ: yàn wọ́n se olórí: lórí ẹgbẹ̀rún-ẹgbẹ̀rún, ọgọ́rùn-ún-ọgọ́rùn-un, àádọ́ta-àádọ́ta àti mẹ́wàá-mẹ́wàá.
Jẹ́ kí wọn ó máa ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn ni gbogbo ìgbà, ṣùgbọ́n jẹ́ kí wọn mú ẹjọ́ tí ó bá nira fún wọn láti dá tọ̀ ọ́ wá; kí wọn kí ó máa dá ẹjọ́ kéékèèkéé. Èyí ni yóò mú iṣẹ́ rẹ rọrùn, wọn yóò sì máa ràn ọ́ lọ́wọ́ lórí ìdájọ́ ṣíṣe.
Mósè sì yan àwọn ènìyàn tí wọ́n kun ojú òsùwọ̀n nínú gbogbo Ísírẹ́lì; ó sì fi wọ́n ṣe olórí àwọn ènìyàn, olórí ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rùn, ọgọ́rùn ún ọgọ́rùn ún, àádọ́ta-àádọ́ta, àti mẹ́wàá-mẹ́wàá.