“Igi akasia ni kí o fi ṣe pẹpẹ, kí ó gùn ní ìwọ̀n igbọnwọ marun-un, kí ó sì fẹ̀ ní ìwọ̀n igbọnwọ marun-un; kí òòró ati ìbú pẹpẹ náà rí bákan náà, kí ó sì ga ní ìwọ̀n igbọnwọ mẹta.
Fi idẹ ṣe ìkòkò láti máa kó eérú orí pẹpẹ sí, fi idẹ ṣe ọkọ́, àwo kòtò, ọ̀kọ̀ tí wọ́n fi ń gún ẹran ẹbọ ati àwo ìfọnná, idẹ ni kí o fi ṣe gbogbo àwọn ohun èlò pẹpẹ náà.
Bákan náà, aṣọ tí o óo ta sí ẹ̀gbẹ́ àríwá àgbàlá náà yóo gùn ní ọgọrun-un igbọnwọ, àwọn òpó ti ẹ̀gbẹ́ náà yóo jẹ́ ogún bákan náà, pẹlu ogún ìtẹ́lẹ̀ tí a fi idẹ ṣe, ṣugbọn fadaka ni kí o fi ṣe ìkọ́ ati òpó wọn.
Ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà yóo ní aṣọ títa kan tí yóo gùn ní ogún igbọnwọ, aṣọ aláwọ̀ aró, èyí tí ó ní àwọ̀ elése àlùkò ati àwọ̀ pupa fòò ati aṣọ ọ̀gbọ̀ ni kí o fi ṣe aṣọ títa náà, kí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí etí rẹ̀, kí ó ní òpó mẹrin ati ìtẹ́lẹ̀ mẹrin.
Gígùn àgbàlá náà yóo jẹ́ ọgọrun-un igbọnwọ, ìbú rẹ̀ yóo jẹ́ aadọta igbọnwọ, gíga rẹ̀ yóo sì jẹ́ igbọnwọ marun-un pẹlu aṣọ títa tí a fi aṣọ ọ̀gbọ̀ ṣe ati ìtẹ́lẹ̀ idẹ.
Yóo wà ninu àgọ́ àjọ, lọ́wọ́ ìta aṣọ títa tí ó wà níwájú àpótí ẹ̀rí, kí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ máa tọ́jú rẹ̀ níwájú OLUWA láti àṣáálẹ́ títí di òwúrọ̀. Kí àwọn eniyan Israẹli sì máa pa ìlànà náà mọ́ títí lae, láti ìrandíran.